NDLEA mú olórí àwọn olóògùn olóró tó jẹ́ agbálẹ̀ ní pápákọ̀ òfúrufú Eko

Oríṣun àwòrán, @DejiAdesogan
Ajọ to n gbogun ti egboogi oloro ni Naijiria, NDLEA, ti fi ṣikun ofin mu agbalẹ kan ni papakọ ofurufu Muritala Muhamed niluu Eko.
Ninu atẹjade kan ti NDLEA fi lede, o ni afurasi naa, Ohiagu Sunday, ni olori ẹgbẹ to n ṣagbatẹru oogun oloro ni papakọ ofurufu naa.
Sunday, to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn lati ipinlẹ Imo, jẹ oṣiṣẹ papakọ ofurufu naa gẹgẹ bii agbalẹ, ki aṣiri iṣẹ laabi to n ṣe nibẹ to tu.
NDLEA ni ọwọ tẹ afurasi ọhun lẹyin ti wọn ti kọkọ mu ọkunrin kan Obinna Jacob Osita, to n ririnajo lọ si orilẹ-ede UAE.
Gẹgẹ bii ohun ti NDLEA so, egboogi igbo ti iwọn rẹ le ni kilo mẹrin ni wọn ka mọ Osita lọwọ, eyii to gbe pamọ sinu apo gaari ati ede.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Yatọ si Ohiagu, wọn tun ti fi ṣikun ofin mu ẹlomiran to tun jẹ ọkan lara awọn ẹmẹwa rẹ ni papakọ ofurufu naa.
NDLEA ni iwadii awọn fi han pe ọkunrin kan to n ṣowo egboogi oloro ni Dubai lo bẹ ọkunrin miran lọwẹ lati ba oun gbe igbo wa si ilu naa, eyii to kesi Ohiagu lati ṣamọna bi ọkunrin ọhun yoo ṣe ri ọna lọ ni papakọ ofurufu naa ti ọwọ ko fi ni tẹ, amọ ọrọ bẹyinyọ.
Yatọ si awọn eeyan wọnyii, NDLE tun ni ọwọ awọn tẹ awọn afurasi mii to n fi igo ẹlẹrindodo Viju ati Fearless gbe oogun oloro lọ siluu Dubai.
Lara wọn ni Jonah Chukwuemeka ti wọn ka koro tramadaol 1,195 mọ lọwọ.
Bẹẹ naa ni wọn tun gbẹsẹle koro tramadol ti iye rẹ to 119,500 ti awọn kan fi ranṣẹ lati orilẹ-ede Pakistan.
Ẹwẹ, ọga agba ajọ NDLEA, Brig. Gen. Mohamed Buba Marwa, ti kan sara si awọn oṣiṣe rẹ fun iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe lati fọ ilu mọ lọwọ oogun oloro.












