Wọ́n ṣá alága ẹgbẹ́ ọlọ́kọ̀ èrò pa l‘Eko lásìkò táwọn jàǹdùkú fẹ́ gbàkóso gáréèjì ọkọ̀

Awọn eeyan to n sare lọ

Oríṣun àwòrán, RSS

Rogbodiyan bẹ sil nilu Eko lọjọ Aiku ana, ti ọrs naa si di ni ti ori yọ, o dile.

Wahala naa lo waye lati ọdọ awọn ọmọ ẹgbẹ ọlọkọ ero ti wọn fẹ gba akoso gareeji ọkọ to wa ni agbegbe Mile 12 nilu Eko.

Wahala ati gba akoso gareeji naa lo mu ki awọn ọmọ ẹgbẹ ti inu n bi maa yinbọn soke lakọlakọ lasiko isẹlẹ naa, bakan naa ni wọn tun n sa ada pẹlu.

Lasiko rogbodiyan yii, ẹmi eekan kan lara awọn ọmọ ẹgbẹ ọlọkọ ero, tii tun se alakoso gareeji ọkọ naa, Sulaimon Onaolapo ba isẹlẹ naa lọ.

Onaolapo, ti inajigẹ rẹ n jẹ Arikuyeri, la gbọ pe wọn sa yanna-yanna pẹlu ada, ti awọn janduku apaniyan naa si sa lọ.

Arikuyeri yii ni wọn lo jẹ alatilẹyin alaga tẹlẹ fun ẹgbẹ awakọ NURTW ni Eko, Alhaji Musiliu Akinsanya, ti ọpọ eeyan n pe ni MC Oluomo

A ti mu ohun gbogbo pada bọ sipo - Ọlọpaa Eko

Alukoro ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ti wa fidi isẹlẹ naa mulẹ, to si ni alaafia ti n pada jọba lagbegbe naa.

Bakan naa ni awọn ikọ digboluja tileesẹ ọlọpaa nilu Eko, ti wọn n pe ni Rapid Response Squad naa fidi isẹlẹ ọhun mulẹ loju opo Twitter rẹ.

Ikọ RRS ni ohun gbogbo ti pada bọ sipo ni Mile 12, tawọn eeyan si n rin bo se yẹ.