Ìwọ́de gbòde lórí bí ìjọba ṣe tú 11 afipábánilòpọ̀ sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n

Oríṣun àwòrán, EPA
Iwọde alagbara ti n waye kaakiri orilẹede India lati tako ipinnu ijọba lori bo se fun awọn ẹlẹwọn mọkanla nidande.
Awọn ẹlẹwọn mọkanla naa ni wọn ju si ẹwọn gbere nitori bi wọn se pawọpọ fipa ba obinrin musulumi kan, Bilkis Bano lopọ.
Ko tan sibẹ o, eeyan mẹrinla ninu ẹbi obinrin naa ni wọn tun seku pa lasiko ifẹhonuhan ẹsin to waye nilu Gujarat lọdun 2002.
Awọn ọkunrin naa ni wọn fun ni idande lẹyin ti wọn ti lo ọdun mẹẹdogun lọgba ẹwọn.
Se ni awọn ọkunrin ati obinrin n pariwo loju popo, ti wọn si n rọ ijọba lati yi ipinnu rẹ lori idande awọn afipabanilopọ naa pada.
Wọn ko ka asa ifipanilopọ kun ohun ti ko tọ mọ - Oluwọde
Gbajumọ osere tiata lobinrin lagbo sinima India, to tun jẹ ajafẹtọ ẹni, Shabana Azmi naa ti wa sọrọ lori isẹlẹ naa.
Nigba to n bawọn akọroyin AFP sọrọ nilu Delhi, Sabana ni "ohun to sẹlẹ si Bilkis Bano yii ati ohun to sẹlẹ si mọlẹbi rẹ, a ko le fara mọ.
A ko le fara mọ ki iru awọn isẹlẹ yii maa waye ni orilẹede wa, idi si ree ti gbogbo wa fi jade lati fi ohun sọkan lori rẹ.”
Ninu ọrọ Aditi, tii se ọkan lara awọn akẹkọ to n fi ẹhonu han ni "Asa ki awọn ọkunrin maa huwa idẹyẹsi sawọn obinrin ati ki awọn ọkunrin maa dari ilu, lai gba obinirn laaye ti wa lekenka, to si ti di baraku.
Koda, o buru jai debi pe awọn ohun ti ko dara, lo ti n di ohun to dara bayii, ti asa fifi ipa bawọn obinrin lopọ ti wa di ohun tọpọ eeyan ko ka kun mọ rara.”
Ọgọrun osisẹ-fẹyinti kọwe ẹhonu ọtọọtọ sijọba lati tako fifun afipabanilopọ mọkanla ni idande kurpo lẹwọn
Nibayii, awọn osisẹfẹyinti to to ọgọrun lo ti kọwe ọtọọtọ si adajọ agba lorilẹede India lori ipinnu ijọba naa.
Ninu iwe naa ni wọn ti n la a ye adajọ agba lori ipa buruku ti igbesẹ fifi awọn afipabanilopọ naa silẹ lọgba ẹwọn yoo ni lori aabo to tọ si gbogbo obinrin.
Ọjọ Kẹẹdogun osu Kẹjọ ni ijọba Gujarat kede igbesẹ rẹ lati tu awọn ẹlẹwọn mọkanla naa silẹ.
Igbesẹ idande fawọn ẹlẹwọn naa ni ijọba Gujarat se lasiko ti orilẹede India n se ajọyọ ọdun marundinlọgọrin to gba ominira.
Wayi o, fidio kan ti jade sori ayelujara nibi ti awọn ọkunrin naa ti to niwaju ọgba ẹwọn Godhra.
Nibẹ si ni awọn mọlẹbi wọn ti n fun wọn ni suuti, ti wọn si n fi ọwọ kan ẹsẹ wọn, eyi tii se ami pe wọn bọwọ fun wọn.
Ẹni ti wọn fipa ba lopọ naa, Arabinrin Bano ni ipinnu lati tu awọn ọkunrin afipabanilopọ naa silẹ, ti mu ki igbagbọ oun ninu idajọ ododo maa mi.
















