Bí mo ṣe dọ̀bàlẹ̀ fún MC Oluomo tún sínà ẹ̀bùn ilẹ́ fún mi - Olaiya Igwe

MC Oluomo ati Olaiya Igwe

Oríṣun àwòrán, Premium Times

Agba oṣere, Ebun Oloyede ti ọpọ mọ si Olaiya Igwe, ti sọ idi to fi dọbalẹ fun alaga igbimọ to n ṣakoso awọn ibudokọ nipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya MC Oluomo.

Ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022 ní MC Oluomo, fun Olaiya Igwe ni ẹ̀bùn ọkọ ayọkẹlẹ Mercedes Benz, fun ayẹyẹ ọjọ ibi.

Fidio bo ṣe fun ni ẹ̀bùn naa lọ kaakiri ori ayelujara, to si safihan bi agba oṣere naa ṣe dọbalẹ, to si n yira nilẹ niwaju oloore rẹ.

Ọkàn lara awọn ọmọkùnrin MC Oluomo, lo first fidio naa si ori ayelujara.

Botilẹ jẹ pe idupẹ oore ni Ọgbẹni Ebun Oloyede fi idọbalẹ naa ṣe, iwa aimọkan ni àwọn eeyan kan ka a si. Ọpọ gbagbọ pe ko yẹ ko dọbalẹ fun MC Oluomo, nitori pe o dagba juu lọ ni ọjọ ori.

Bakan naa ni awọn kan n sọ pe nitori atilẹyin ti oṣere naa n ṣe fun oludije si ipo aarẹ, lati inu ẹgbẹ́ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu, ti MC naa n ti lẹyin, lo mu ko fun ni ọkọ.

Sugbọn ṣa, Ọgbẹni Oloyede sọ pe oloore oun lati ọjọ pipẹ ni MC jẹ.

Olaiya ṣalaye ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu oserebinrin, Kemi Afolabi, lori ayelujara Instagram pé, pe ariwo ọjà lasan mi ọrọ ti o wọn n sọ si oun lori ayelujara nitori pe titi lai ni oun jẹ gbèsè ọpẹ lọdọ MC.

Ọjọbọ ni ifọrọwerọ naa waye.

O ni yatọ si ọkọ ayọkẹlẹ ti MC fun oun, ẹnikan to n gbe nilẹ òkèèrè tun fun oun ni ilẹ lẹyin rẹ.

O ni bi oun ṣe fi imoore han, lo mu ki onitọhun tun fun oun ni ilẹ̀.

"Nkan ti ko ye mi ni bi awọn eeyan kan ṣe n binu si ọna ti oun gba dupẹ oore."

O ni ko si bi eeyan ṣe le ga tó, eeyan kii ga ju ọpẹ lọ.

Olaiya sọ pe oun fi ara MC Oluomo dupẹ lọ́wọ́ Ọlọ́run ni.

Igba àkọ́kọ́ kọ niyi ti iroyin jade nípa bi alaga nigba kan ri fun ẹgbẹ́ awakọ eero nipinlẹ Eko, Musiliu MC Oluomo, fun àwọn osere tiata Yoruba ni ẹbun.