Yollywood: Baba Wande, Kareem Adepoju, Jide Kosoko, Taiwo Hassan, Yinka Quadri àti Alapinni jẹ́ díẹ̀ nínú àwọn àgbà òṣèré májẹ́kòbájẹ̀ àsìkò yìí

Awon agba osere

Oríṣun àwòrán, Others

Iriri kọja ẹgbẹ abẹwu ni ọrọ awọn agba osere kọọkan jẹ.

Ohunkohun ti eeyan ba yan láayo, o dara lati fi gbogbo ara ṣe e ki o le moke nibẹ.

Opọ agba osere lo ti fi ara ṣiṣẹ ki iṣẹ tiata to de ibi to de duro yii, awọn miran ri re ibi agba n re nigba ti awon mii si wa lori oke eepe.

Diẹ ninu awọn ọpọ osere titata to si wa laye di isinyii ni a ti ri awon ti ọpọ n pe lorukọ ere ori itage bii: Jide Kosoko, Baba Wande, Ogogo, Kura, Oga Bello ati Alapinni Oosa yatọ si awọn mii ti won tun n sise karakara.

1. Kareem Adepoju ti ọpọ mo si Baba Wande:

Baba Wande bẹrẹ si ni di gbajumo leyin to se ere Ti Oluwa ni ilẹ ni ọdun 1993 nigba to kopa gege bii Oloye Otun.

Lara awon ere to ti se ni Ayo ni Mo fe, Abeni, Arugba, Igbekun, Obuko Dudu, Ika Lomo Ejo, Enu Eye, Oba bi Olorun ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oloye Karem Adepoju ti se ọpọlọpọ ere ori itage, ere sinima ati ere agbelewo.

Iriri to pọ ni Oloye yii ni to si fi n kọ awon ọdọ osere isinyi.

Baba Wande

Oríṣun àwòrán, @Kareem Adepoju

Àkọlé àwòrán, Baba Wande

2: Jide Kosoko:

Jide Kosoko jẹ ọkan lara agba oṣere ti wọn bi ere ṣiṣe mọ lati ibẹrẹ.

Ojọ kejila, osu kinni ọdun 1954 ni a bii sile ọla nibi to ti kawe to si bẹrẹ ere itage sise lati ọmọ kekere ni Ebutte Metta ni agbegbe to dagba si ni ilu Eko.

O kawe gboye ninu ẹkọ 'Business Administration' lati ile ẹkọ Yaba College of Education ni ipinlẹ Eko.

Leyin naa lo lọ kọsẹ ere itage sii ni Fasiti Olabisi Onabanjo ni Ago Iwoye.

Jide Kososko

Oríṣun àwòrán, @Jide Kosoko

Àkọlé àwòrán, Jide Kososko

Jide Kosoko naa bẹrẹ ere tiata pẹlu awọn alarinjo Ifelodun Traveling Theatre Group.

Diẹ lara ere ti Jide Kosoko ti kopa ni ede Yoruba ni: 'Eje Adegbenro', 'Durodola', 'Koseegbe', 'Oro Nla' nigba ti awọn mii lede oyinbo ni 'King of Boys', 'The Bling Lagosian', 'Reunion', ati awon mii.

Awọn ọmọ bibi rẹ obinrin meji naa ni wọn ti darapọ mọ baba wọn lẹnu iṣẹ ere itage. Awon naa ni Sola ati Bidemi Kosoko.

3: Taiwo Hassan- Ogogo Kulodo

Taiwo Hassan

Oríṣun àwòrán, @Ogogo

Àkọlé àwòrán, Taiwo Hassan

Agba Osere yii jẹ ọkan lara awọn agba oṣere ti aye n fẹ lasiko yii.

Opọ maa n yin fun ọgbọn atinuda to fi maa n gbe ero rẹ kalẹ ninu ipa ti wọn ba fun Ogogo ṣe.

Wọn maa n sọ pe kii fẹ ko ipa ti yoo ti maa tẹnubọ osere binrin mii lẹnu rara.

Àkọlé fídíò, Mistura Asunmo, Iya 2D:1959 ni mo bẹ̀rẹ̀ eré ṣùgbọ́n ń kò ní ọkọ̀ ẹyọ kan di ìsìnyí

Ojọ kọkanlelọgbọn, osu kẹwaa, ọdun 1959 ni wọn bi Ogogo ni ilu Ilaro.

O lọ sile ẹkọ Christ Church School ati Yaba Technical College ninu iṣẹ atun ọkọ ṣe ti won pe ni 'automobile mechanic'.

Àkọlé fídíò, Emeritus Ayo Bamgbose: Ibánújẹ́ ni ojú yẹpẹrẹ tí ìjọba fi n wo olùkọ́ báyìí jẹ́ fún mi

Ogogo ba ileeṣẹ Water Corporation sise fun ọdun mẹtala lati 1981 si 1994 ko to darapọ mọ awọn oṣere.

Diẹ lara awọn ere ti Ogogo ti kopa ni 'Bolode O'ku', 'Apadi', 'Owo Blow', 'Obinrin So Wa Nu

Taiwo Hassan fẹ iyawo meji o si sabiyamọ ọmọ mẹrin.

4. Adebayo Salami- Oga Bello:

Adebayo Salami

Oríṣun àwòrán, @Adebayo Salami

Agba ọjẹ ọṣere ni Adebayo Salami lati ipinle Kwara.

A bii ni ọjọ kẹsan an, oṣu karun un, ọdun 1952 nipinle Eko.

Lati kekere ni o ti bẹrẹ ere itage alarinjo nigba to darapọ mọ Young concert Party ti oloogbe Ojo duro Ladiipo.

Àkọlé fídíò, ASUU Strike effect: Gbogbo à\won tó n ṣiṣẹ́ nítorí ileẹ̀kọ́ sọ̀rọ̀ lórí ìṣòro wọn látìgbà

To pada yi oruko pada si Awada kerikeri nigba ti Oga Bello di adari won leyin iku Ojo Ladiipo.

Ajani Ogun ni fiimu akọkọ to gbe Oga Bello sita ni eyi ti oun naa geb Ogun Ajaye sita.

Àkọlé fídíò, Gẹ́gẹ́ bí àṣà, mo ti mọ̀ tipẹ́ pé mo máa jẹ ọba Akinghare II - Oba Oloyede

O ti se ọpọlọpọ fiimu to si ti kopa ninu ogunlọgọ fiimu.

Awọn ọmọ rẹ naa si ti darapọ mọ ọ ninu iṣẹ ere itage bayii.

Lara wọn la ti ri: Femi Adebayo, Tope Adebayo ati bẹẹ bẹẹ lọ.

5. Yinka Quadri:

Yinak Quadri

Oríṣun àwòrán, @Yinka Quadri

Yinka Quadri ti ọpọ n pe ni Kura jẹ agba oṣere.

O jẹ Oludari ere ati olootu ere sinima.

A bi Yinka Quadri ni ọjọ kẹfa, osu kẹsan an, ọdun 1959 ni agbegbe Lagos Island nipinle Eko.

Àkọlé fídíò, Oluwo Jogbodo Orunmila: Ẹsẹ odù Ifa ló fi ṣúre fún ọmọ Nàíjíríà ní àyájọ́ ọdún tuntun

O jẹ ọmọ ilu Oro nipinle Kwara. Oun naa ni Agbaakin ilẹ̀ Oro ni ipinle Kwara.

O lọ sile ẹkọ St Catholic School ni Idumagbo ati Christ High School ni Ebute Elefun nipinle Eko.

Àkọlé fídíò, Ìran kan si ìkejì ló n gbèrò láti ṣe ìrú ìgbéyàwo àjùmọ̀ṣe 'Shao' fọ́mọ wọn

Odun 1976 ni Yinka Qudri bẹrẹ ere sise pẹlu awon ọrẹ rẹ kan bii Taiwo Olayinka eyi ti wọn pe orukọ rẹ ni Afopina Theatre Group.

Yinka Qudri kopa ninu ere olọsọọsẹ ati awọn ere onise mii bii Abulesowo, Bolode O ku, 'Apadi', 'Egbinrin Ote', 'Kutupu' ati béé béé lọ.

Yinak fẹ iyawo o si bimọ ati ọmọ ọmọ pẹlu awọn ọmọ ori itage to pọ.

6. Ganiu Nafiu: Alapinni:

Alapinni Oosa

Oríṣun àwòrán, @Alapinni Oosa

Ọpọ nkan nipa agbaọjẹ oṣere ni Ganiu Nafiu ti ọpọ mọ si Alapinni Oosa.

Ko si ẹni to le fidi ọjọ ori rẹ mulẹ nipato ṣugbon wọn gba pe o ti le ni ọgọrin ọdun.

O jẹ ẹlẹsin musulumi ṣugbon o ni imọ kikun nipa ẹsin abalaye.

Àkọlé fídíò, Alapinni Oosa ṣàdúrà fún gogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?

Opo ololufẹ Alapinni Oosa ni wọn maa n gbadun ohun rẹ to yatọ.

O ti le logoji ọdun sẹyin to ti n ṣe ere itage kaakii.

Opo igba ni Rafiu Ganiyu maa n ṣe babalawo ninu ere Yoruba.

Àkọlé fídíò, Iya àwọn aderinposonu ìbejì tí ọ̀pọ̀ mọ sì Twinz Love ṣàlàyé ìrìnàjò rẹ pẹlu awọn ọmọ rẹ

Saaju ko to maa ṣere lo ti kọkọ n ṣe awada kiri adugbo pẹlu awọn ọrẹ rẹ kan.

Lẹyin iku ọkan ninu wọn lo gba ile keu lọ ko to da ẹgbẹ tirẹ silẹ ni 1979.

O pada ba awọn agba ọjẹ oṣere bii Akin Ogungbe, Ray Eyiwumi ati awọn mii ṣere.

Àkọlé fídíò, Ìyàwó lè lo ọwọ́ rẹ̀ fi ba ọkọ ṣeré lásìkò Halaada rẹ̀, èyí kò ba ẹ̀sìn jẹ́- Aafa Abdullat

Ni Ipari, Awọn agba ọjẹ osere yii wa lara awọn to n mu itẹsiwaju ba agbo ere oniṣe Yoruba.

Ki ogo Yoruba maa tẹsiwaju lo wu awọn ololufẹ ede naa ninu iṣẹ akada ati lagbo idanilaraya.