''Ó ti di òfin, tísà ìjọba kankan kò gbọdọ̀ fi ọmọ rẹ̀ sí iléẹ̀kọ́ aládàni''

Oríṣun àwòrán, Others
Ijọba ipinlẹ Ondo ni awọn koju oro si awọn tisa ilẹẹ̀kọ to n mu awọn ọmọ wọn lọ si ileẹkọ aladani.
Alaga Ajọ to n risi eto ẹkọ nipinlẹ Ondo, arakunrin Victor Olabimtan lo sọ eyi lasiko to n ṣepade pẹlu awọn olukọ agba awọn ileẹkọ alakọbẹrẹ ni ilu Akurẹ
Olabintan ni awọn ti sọ di ofin bayii ki tisa kankan ma mu ọmọ wọn lọ si ileẹkọ aladani.
O ni igbesẹ to buru jai ni, ki oṣiṣẹ ijọba fi ọmọ rẹ si ileẹkọ aladani.
Bakan naa lo paṣẹ fun awọn akọwe ijọba ni ijọba ibilẹ mejidinlogun lati fi ẹjọ tisa to ba rufin naa ṣun.
Amọ o ni o ṣeni laanu pe awọn ọmọde ko lọ si ileẹkọ ijọba mọ, ti iye wọn si n kere si
Akeredolu buwọ́lu ìgbéga lẹ́nu ìṣẹ́ fún àwọn olùkọ́ tó lé ní 2000
Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ti buwọlu igbega lẹnu iṣẹ fun awọn oṣiṣẹ ileẹkọ alakọbẹrẹ ni ipinlẹ Ondo.
Alaga Ajọ to n risi eto ẹkọ nipinlẹ Ondo, arakunrin Victor Olabimtan lo sọ eyi lasiko to n ṣepade pẹlu awọn olukọ agba awọn ileẹkọ alakọbẹrẹ ni ilu Akurẹ
Olabimtan to pin iwe igbega naa fun awọn olukọ to le ni ẹgbẹrun un meji, ti marunlelọgọrin ninu wọn si gba igbega lọ si ipele mẹrinlelogun (Level 16), eleyii to yẹ fun ipo permanent secretary.
O ni idi ti wọn fi gbe igbesẹ naa ni lati fun awọn olukọ ni eto igbayegbadun fun awọn olukọ nipinlẹ Ondo.












