Ṣọ́ọ̀bù alájà mẹ́ta tó wọ́ mú ẹ̀mí ènìyàn méjì lọ ní Abuja

Aworan

Oríṣun àwòrán, Other

Ajọ to n risi ọrọ pajawiri ni Naijiria ti fi idi rẹ mulẹ pe eniyan meji ti ku, ti wọn si doola ẹmi eniyan marun lẹyin ti sọọbu alaja mẹta wo lulẹ ni agbegbe Kubwa ni ilu Abuja.

Iroyin gbe e jade bii ṣọọbu alaja mẹta ti wọn ṣẹṣẹ nkọ naa ṣe wopalẹ ni alẹ Ọjọbọ.

Lasiko ti wọn sọ iye awọn to gbẹmi ni Ajọ to n risi ọrọ pajawiri ni ilu Abuja FEMA ni wọn ti gbe oku awọn ti wọn ba iṣẹlẹ naa lọ si mọsuari.

O ni awọn pari gbogbo igbiyanju idoola ẹmi lẹyin ti awọn ri eniyan marun un yọ labẹ ile to wo naa, ti mẹta ninu wọn farapa lọpọlọpọ.

Amọ meji ninu wọn ti ko farapa pupọ ti pada si ile wọn lẹyin ayẹwo ni ile iwosan Kubwa District Hospital.

Bakan naa lo ni awọn mọlẹbi awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ ti yoju ti awọn yoo si ṣeranwo nipa isinku wọn.

Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye re e...

Aworan

Oríṣun àwòrán, Other

‘Agbẹnusọ Ajọ FEMA ni o ṣeni laanu pe ṣọọbu naa wopa awọn eniyan amọ ohun akọkọ to faa nipe ẹni to n kọ ibẹ tako ofin gbigbe ile duro.’’

‘’O ni biotilẹ jẹpe kikọ ile naa gba iwẹ aṣẹ , amọ ohun ti wọn sọ wipe wọn fẹ kọ kọ ni wọn kọ sibẹ.’’

‘’Ohun to ṣẹlẹ ni pe ẹni to ni ṣọọbu alaja naa fi ọpọlọpọ bulọọku si, eleyii ti ko si ninu ilakalẹ ile ti wọn dẹ kọ’’

Eyi mu ki ile naa wu wo ju bo ṣe yẹlọ, ti o si wo lulẹ.’’

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ nibẹ nigba ti ile dawo, Olayinka ni oju oun bayii ni ile naa dawo.

O ni awọn meje ni wọn n ṣiṣẹ nibẹ ni nkan bi aago mọkanla alẹ, ti marun un ninu wọn si ti sun amọ ti awọn meji n ṣiṣẹ lọ.

O ni sadede ni ile naa wo lulẹ amọ oun ri pe eru to wọ lu oun ko rin oun mọlẹ, lo ṣe rapalẹ kuro ni abẹ ibẹ.

O ni lasiko ti oun rapala naa ni oun ri ina lọọkan ni ountọ paṣẹ ina naa jade, ti ohun si bọ sita.

Amọ o ni lẹyin ti oun jade tan ni oun bẹrẹ si ni gbo igbe awọn eniyan ni abẹ ile to wo naa.