Mi ò ṣé ìpàdé pẹ̀lú àwọn gómìnà PDP G-5 ní London – Tinubu

Aworan Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Others

Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Bola Tinubu ti sọrọ lori awuyewuye to n lọ pe awọn gomina kan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ti buwọlu oun gẹgẹ bi ẹni ti wọn maa dibo fun.

O ni gbogbo iroyin pe awọn ṣe ipade pọ niluu London ko yẹ ko jẹ ohun ti yoo mu ẹjọ dani nitori gẹgẹ bi oloṣelu ko si ẹni ti oun ko le ba ṣe ipade.

Tinubu ni irọ to jina sotọ ni iroyin naa nitori ko si nnkan to jọ mọ bẹ rara.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Tunde Rahman fi lede ni iroyin ofege nipa ipade naa lo ni erongba buruku, ti o yẹ ki wọn yi danu.

O tẹsiwaju pe ohun ti oun gbajumọ lasiko yii ni ipolongo oun nikan bayii ati bi oun yoo ṣe bori ninu eto idibo aarẹ to n bọ, eyi ti yoo fun ni anfani lati mu ileri to ṣe fun awọn orilẹede Naijiria wa si imusẹ.

Tinubu ni oun wa si ilu London lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kejila lati simi fun igba diẹ ko to morile orilẹede Saudi Arabia fun Umrah.

“Gẹgẹ bii mo ṣe maa ṣe ni ipari ọdun, mo gba isinmi lati lọ si Umurah.

“Nigba ti mo wa niluu London, mo n ka awọn iroyin ofege pe mo ṣe ipade pọ pẹlu awon gomina lati ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.

“Erongba iroyin ofeege yii no ko dara rara, awọn oloṣelu kan lo fẹ tẹ arawọn lọrun.

Tinubu ni gẹgẹ oloṣelu, oun ni ẹtọ lati ṣe ipade pẹlu ẹnikẹni ti yoo ba wulo fun iponlogo oun ati bii oun yoo ṣe di aarẹ.

A ò tíì tọwọ́bọ àdéhùn pẹ̀lú olùdíje sípò ààrẹ kankan – Àwọn gómìnà G5

Awọn gomina G5

Oríṣun àwòrán, Twitter

Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers, Nyesom Wike ní òun àti àwọn gómìnà akẹgbẹ́ rẹ̀ mẹ́rin tó kù tí wọ́n ń pe ara wọn ní G5 kò ì tíì fẹnukò pẹ̀lú olùdíje sípò ààrẹ kankan gẹ́gẹ́ bí ẹni tí àwọn máa tẹ̀lé ní ọdún 2023.

Àwọn G-5 ọ̀hún ni gómìnà Seyi Makinde ti ìpínlẹ̀ Oyo, Samuel Ortom ti Benue, Ifeanyi Ugwuanyi ti Enugu, Okezie Ikpeazu ti Abia àti Nyesom Wike fúnra rẹ̀.

Ẹ ó rántí pé láti ìgbà tí ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ti ṣètò ìdìbò abẹ́nú láti yan ẹni tí yóò gbé àsíá ẹgbẹ́ náà níbi tí Alhaji Atiku Abubakar ti gbégbá orókè ni awuyewuye ti ń wáyé láàárín àwọn gómìnà náà àti PDP.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ohun tí wọ́n ń bèèrè fún ni pé kò yẹ kí ipò ààrẹ wá láti ẹkùn árìwá kí alága ẹgbẹ́ náà tún wá láti árìwá tí wọ́n sì ní kí alága ẹgbẹ́ Iyorcia Ayu kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ tí wọn kò sì ṣe àtìlẹyìn fún olùdíje wọn.

Láti ìgbà náà ni ẹnu ti ń kùn wọ́n wí pé àwọn gómìnà ń gbèrò láti ṣe àtìlẹyìn fún olùdíje mìíràn àti wí pé ìdúnàádúrà ti ń wáyé láàárín wọn àti àwọn olùdíje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú mìíràn.

Ìròyìn tilẹ̀ ti ń lọ pé wọ́n ti fẹnukò pẹ̀lú olùdíje kan pàtó.

Àmọ́ gómìnà náà ti wá ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ọ̀rọ̀ náà wí pé àwọn kò ì tíì buwọ́lu àdéhùn kankan pẹ̀lú olùdíje kankan.

Wike nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ìfilọ́lẹ̀ òpópónà Eneka-Igbo ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló mọ̀ wí pé tí òun bá fẹ́ ṣe nǹkan, òun máa ṣe ni.

Ó ní tí òun bá fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ lórí ẹni tí àwọn máa dìbò fún gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Nàìjíríà òun máa fi ìpinu òun léde àti pé òun kò ní kọ̀ láti gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ àwọn olólùfẹ́ òun.

Bákan náà ló rọ àwọn ènìyàn láti fi àwọn gómìnà náà lọ́rùn sílẹ̀ àti òun fẹ́ gbádùn ara òun pẹ̀lú àwọn ẹbí òun nígbà tó jẹ́ wí pé òun kò du ipò kankan lọ́dún tó ń bọ̀.

Wike tún fẹ̀sùn kan alága ẹgbẹ́ PDP pé ó ń yọ ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn gómìnà APC àmọ́ tó kọ̀ láti mú ìlérí ṣẹ pé alága ẹgbẹ́ àti ààrẹ kò ní wá láti ẹkùn kan náà.