Alákoso ìpàdé orin 'Concert' fojú ba ilé ẹjọ́ nítorí pé ẹni mẹwàá kú

Aworan

Oríṣun àwòrán, AFP

Ile ẹjọ kan nilu kampala lorilẹede Uganda ti fi ẹsun ẹlẹsẹ mẹsan an kan Abbey Musinguzi ẹni ti o ṣe konkari apejọ orin nibi ti eeyan mẹwaa ti ku.

Abbey Musinguzi farahan niwaju ile-ẹjọ adajọ ti Makindye ni irọlẹ ọjọ iṣegun nibiti o ti ni oun ko jebi awọn ẹsun naa, leyin na ni adajọ paṣẹ ki wonfi i sẹwọn Luzira.

Ara ẹsun ti wọn fi kan ni wi pe o fa ikọlu ni Ile-itaja Freedom City Mall nigba ti o ti awọn ilẹkun to wo inu gbangan freedom mall

Ti o si ṣi ilẹkun kan soso fun awọn oluworan to too egbaawa lati jade eyi ti o fa ikọlu nibiti eniyan ba iṣẹlẹ naa lo.

Ninu awijare Abbey Agbẹjọro rẹ sọ pe onibara oun fojuba ile ẹjọ nitori wi pe o jẹ alatilẹyin fun ẹgbẹ alatako National Unity Platform Robert Kyagulanyi ti ọpọlọpọ eniyan mo si Bobi wine.