Àjọ NEMA ní afurasí agbésùnmọ̀mí tó fẹ́ kọlu bárékè ológun, ni àdó olóró tó so mọ́ra, pa l'Abuja

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri lorilẹede yii, National Emergency Management Agency (NEMA), ti fidi ẹ mulẹ, pe afurasi apaayan-pa-ara ẹ (suicide bomber) ni ẹni ti bọmbu pa l'Abuja.
Ọsan ọjọ Aje ọsẹ yii ni iṣẹlẹ naa waye.
NEMA ṣalaye pe ado oloro ti ẹni naa di mọ ara rẹ lo bu gbaamu to si pa a.
Ninu atẹjade kan ti ajọ NEMA fi si oju opo X wọn, wọn ṣalaye pe iwaju Bareke Abacha, ti a mọ si Mogadishu Cantonement tẹlẹ, ni ibugbamu naa ti waye loju ọna Abuja-Keffi.
Wọn fi kun un pe apaayan-pa-ara rẹ naa fẹẹ yọ wọnu bareke ologun ọhun ni, ki ado to gbe sara too bu gbamu lojiji nibi to ti wa ọna lati wọle.
"Apaayan-pa-ara ẹ naa ku loju ẹsẹ, ẹnikan to n kọja lọ naa si farapa. "
Bẹẹ ni atẹjade NEMA wi.
Ẹka ọlọpaa EOD sare gbe ẹni naa lọ sile iwosan ijọba apapọ, wọn si n bojuto agbegbe naa pẹlu iwadii .
Awọn ọmọ ogun ofurufu ati ti ori omi ni wọn pọ ni bareke ti iṣẹlẹ naa ti waye.
Àwọn ìbúgbàmù àdó olóró tó ti wáyé l'Abuja

Oríṣun àwòrán, @Nigerian Defence
Aabo ko fi gbogbo ara peye niluu Abuja ti i ṣe olu ilu Naijiria, paapaa latigba ti ikọlu awọn Boko Haram ti bẹrẹ to si gbokun si i ni 2010.
Ṣugbọn ṣaa, ado oloro to kọkọ bu gbamu l'Abuja ki I ṣe lati ọwọ awọn Boko Haram.
Awọn ajijagbara Niger Delta,Movement for di Emancipation of di Niger Delta (Mend), lo kọkọ sọ bọmbu si Abuja.
Eyi waye lọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹwaa ọdun 2010.
Itosi gbagede Eagle square, nibi ti awọn eeyan pọ si lati ṣe ayẹyẹ ominira aadọta ọdun Naijiria ni wọn ju ado oloro naa si.
O to eeyan mejila to ku ninu ijamba naa, ọpọ si farapa.
Iṣẹlẹ yii lo ran Charles Okah olori MEND ati Igbakeri rẹ, obi Nwabueze, lọ si ẹwọn gbere.
Ile ẹjọ giga kan l'Abuja lo ran wọn lẹwọn naa loṣu Kẹta ọdun 2018. Ọdun kẹjọ lẹyin ibugbamu naa.
Ìṣẹ̀lẹ̀ apààyàn-pa-ara ẹ̀ to ti waye sẹyin
Iṣẹlẹ akọkọ to ni I ṣe pẹlu ipaayan-pa-ara ẹni l'Abuja, waye lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹjọ ọdun 2011.
Ile nla, United Nations Building ti I ṣe ti Ajọ Iṣọkan agbaye ni ibugbamu naa ti waye.
Apaayan-pa-ara ẹ kan lo wa ọkọ wọnu ile naa, o si kere tan, eeyan mejidinlogun (18) di oku ninu iṣẹlẹ yii.
Awọn Boko Haram kede nigba naa pe iṣẹ ọwọ awọn ni.
Lọjọ ọdun Keresimesi, ni 2011 kan naa, eeyan marundinlogoji (35), padanu ẹmi nigba ti ado oloro bu gbamu ni St Theresa Catholic Church, Madala.
Ilu kekere to wa ni aala Abuja ati ipinlẹ Niger ni Madala.
Ibudokọ Nyanya ni ado oloro ti bu gbamu lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹrin ọdun 2014.
Ko din ni eeyan mejidinlaadọrun-un (88) to ku .
Nigba to tun di ọjọ akọkọ ninu oṣu Karun-un ọdun 2014 kan naa, wọn tun ju bọmbu si ibudokọ kan to wa nitosi ti akọkọ.
Eeyan mọkandinlogun (19) lo tun ba iyẹn naa lọ.
Loṣu Kẹfa, 2014, ibugbamu ado oloro mi-in tun waye nile itaja nla kan lagbegbe Wuse 2.
Bakan naa lọjọ kẹta, oṣu Kẹwaa ọdun 2015, ikọlu ado oloro meji waye lagbegbe kan naa l'Abuja.
Akọkọ ni ti Kuje, ikeji si ni ti Nyanya.
Awọn ilu mejeeji yii ko tobi pupọ, ṣugbọn wọn mule ti igboro Abuja.
Eeyan mejidinlogun (18) lo di oloogbe, nigba ti ọpọ eeyan farapa yanna-yanna.
Ọkan ti ko ti i pẹ ju lo waye lagbegbe Bwari, loṣu kin-ni-ni ọdun 2025 yii.
Eeyan meji lo ku nigba ti ado oloro dun nileewe alakọọbẹrẹ kan.
Lẹyin iṣẹlẹ naa ni awọn ọlọpaa fidi ẹ mulẹ, pe awọn ọkunrin mẹta kan to lọọ ki ẹni to ni ileewe naa lo fa a.
Awọn meji ku, ikẹta wọn farapa pẹlu obinrin ọlọja kan.














