Ẹ̀yin ènìyàn ẹ ṣọ́ra, àìsàn Diphteria tí pa ènìyàn 80 ní Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n risi ọrọ ajakalẹ aarun ni Naijiria ti kede pe aisan Diphtheria ti pa ọmọ ọdun mẹrin ni ilu Abuja.
Aisan naa ti o ma n ran awọn eniyan lọgọọrọ ma n ṣe akoba fun imu ati ọna ọfun awọn eniyan to ba kagbako rẹ.
Eyi yoo fa inira fun eemi nibẹ to si le ṣakoba fun ọkan ati awọn ẹya ara miran.
Awọn ọmọ ọdun meji si ọdun mẹrinla ni aisan naa ba n ba finra.
Iwadii ni ọmọ to ku nitori aarun naa ko gba abẹrẹ ajẹsara.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ninu atẹjade ti ijọba fi lede ni wọn ti ni ọdun to kọja ni aarun naa ti bẹ silẹ kaakiri awọn ilu kọọkan ni Naijiria.
Wọn ni o kere tan eniyan ọgọrin lo ti ku ninu awọn ẹgbarin to ti kagbako aarun naa ni awọn ipinlẹ mẹjọ ni Naijiria.
Awọn ilu ti wọn kede pe aarun naa wa ni ilu Eko, ti aisan naa pọsi ju,ti ipinlẹ Kano si tẹle, ti Abuja si lugbadi arun naa ni ipari Osu Kẹfa, ọdun yii.
Ajọ naa fikun un pe awọn ti wọn ko gba abẹrẹ ajẹsara naa ni iwadii ti fihan pe wọn lugbadi arun naa.
Ileeṣẹ eto ilera ni Naijiria wa kesi awọn araalu lati fi arabalẹ, ki wọn si fito awọn eleto ilera ti wọn ba ti gburo tabi ri awọn ami naa.
Bakan naa ni ajọ naa ni awọn n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ileewosan lati koju aarun naa ki o to tan kalẹ ju bayii lọ.
Kini awọn ami ti yoo farahan ti eniyan ba lugbadi aarun Diphteria
- Aran gbigbona
- Iba
- Aile jẹun daradara
- Ẹnu wiwu
- Aile mi daradara
- Catarrh ati ikọ wiwu
- Ara riro ati ara rirẹ
Kini ọna lati dena arun Diphteria?
Awọn dokita ni ọna kan gboogi lati dena itankalẹ aarun naa laarin agba ati ọmọde ni lati gba abẹrẹ ajẹsara naa.
Wọn ni abẹrẹ yii yoo ba aarun naa ninu ara.
Bakan naa lo pọn dandan ki awọn eniyan ni imọ nipa abẹrẹ ajẹsara fuin awọn ọmọde nitori igbagbọ wa pe eyi yoo koju ikọ wiwu, ẹyin to jẹra ati igbona.












