Èéfín ẹ̀rọ amúnáwá ṣekúpa ọkọ l'Ogun, ìyàwó dèrò ilé ìwòsàn

Aworan awọn ẹrọ amunawa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aworan awọn ẹrọ amunawa
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọkunrin kan, Nwachukwu Ikechukwu, ti padanu ẹmi rẹ bayii latari ẹrọ amunawa ti oun ati iyawo rẹ, Oyin Falodun, tan lalẹ ọjọ Ẹti, ogunjọ, oṣu Kẹsan-an ọdun 2024.

Agbegbe kan ti wọn n pe ni Shogoye, eyi to wa ni Owode Egba, nipinle Ogun ni iṣẹlẹ yii ti waye.

Yatọ si Nwachukwu to di oloogbe nipasẹ eefin ẹrọ amunawa, iyawo rẹ ti wọn jọ sun ninu yara kan naa, fara ko eefin naa pẹlu, ọjọ keji lo too laju nileewosan ti wọn gbe e lọ.

Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀ gan-an?

Gẹgẹ bi SP Omolola Odutola, Alukoro ọlọpaa Ogun ṣe ṣalaye, o ni, “obinrin kan, Oladayo Olasubomi, lo lọ sile awọn tọkọ-taya yii lati fun iyawo ni ẹgbẹrun kan naira owo ajọ ojumọ ti wọn n da.

‘’Nigba to debẹ lo ba oku Nwachukwu nilẹẹlẹ, ti Oyin iyawo rẹ naa si wa lẹgbẹẹ rẹ nibẹ lai mira. Ko si si apẹẹrẹ ifiyajẹni tabi àpá kankan lara wọn.

Obirin naa lo ke gbajare ti wọn fi gbe tọkọ-taya lọ silewosan.”

Odutola ṣalaye pe nigba ti iyawo laju lọsibitu lo pada ṣalaye pe awọn tan ẹrọ jẹnẹretọ lalẹ ọjọ Ẹti, kawọn le ni anfaani lati gba faanu diẹ sara kawọn too sun.

Oyin sọ pe oun beere lọwọ ọkọ oun pe ṣe koun lọọ pa jẹnerọ naa ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ, ṣugbọn o ni koun ma pa a.

Awọn mejeeji gbagbe sun, ohun ti Oyin si pada ri ni pe ọkọ rẹ n gbiyanju lati dide lorii bẹẹdi, ko si ṣee ṣe fun.

Awọn mejeeji ko mọ nnkan kan mọ to fi di pe ọkọ ku, ti iyawo si ba ara rẹ nileewosan lọjọ keji.

Koda, funra jẹnẹretọ ọhun lo pada ku funra rẹ, nigba ti epo tan.

SP Odutola sọ pe iwadii n tẹsuwaju lori iṣẹlẹ yii, bẹẹ ni wọn ti gbe oku oloogbe lọ si ileewosan ijọba to wa ni Owode Egba, ki wọn le ṣe ayẹwo ohun to pa a gan-an.