Iná mọ̀nà-mọ́ná pa ọmọ ọdún 13 l'Ogun, ọlọ́pàá bá òkú rẹ̀ lọ́wọ́ afurasí tó ti gé ọwọ́ rẹ̀ méjèéjì

Ogidan Mustapha ati awọn nnkan ti awọn ọlọpaa ni awọn ba nile rẹ

Oríṣun àwòrán, SP Omolola Odutola

Àkọlé àwòrán, Ogidan Mustapha ati awọn nnkan ti awọn ọlọpaa ni awọn ba nile rẹ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹka to n tọpinpin iwa ọdaran nipinlẹ Ogun ni ọkunrin kan, Ogidan Mustapha, wa bayii, latari ọmọ alabagbe rẹ ti wọn ni o kun oku rẹ wẹlẹwẹlẹ.

Agbegbe odo Igbosoro, Igode, nijọba ibilẹ Sagamu ni ọwọ ti ba afurasi yii ni nnkan bii aago kan aabọ oru ọjọ Ẹti, ogunjọ, oṣu Kẹsan-an ọdun 2024.

Yatọ si ẹsun gige ọwọ oku naa mejeeji, eyi ti i ṣe ọmọbinrin ẹni ọdun mẹtala ti wọn pe orukọ rẹ ni Oriyomi Adegboyega, awọn ọlọpaa sọ pe awọn tun ba ibọn oyinbo meji nile Ogidan.

Bẹẹ ni wọn ba oogun abẹnugọngọ ọlọkan-o-jọkan pẹlu.

SP Omolola Odutola, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ṣalaye ninu atẹjade to fi sita lọjọ Ẹti, ogunjọ oṣu Kẹsan-an ọdun 2024.

'Níbi tó ti ń ju òkú tó fi ẹni wé sí ẹ̀gbẹ́ odò ni ọwọ́ ti bà á'

Alukoro olopaa Ogun, SP Omolola Odutola

Oríṣun àwòrán, SP Omolola Odutola/ Facebook

Àkọlé àwòrán, Alukoro olopaa Ogun, SP Omolola Odutola

Gẹgẹ bi SP Odutola ṣe ṣalaye, o ni ajọṣepọ fijilante ati ọlọpaa lo jẹ ki ọwọ ba Ogidan.

''Awọn fijilante lo fi to ọlọpaa leti, pe ẹnikan n rin irin ifura ni bebe odo Igbosoro, o si gbe ẹni to di nnkan sinu rẹ lọwọ loruganjọ.

''Nigba ti awọn fijilante sun mọ ọn, wọn yẹ ohun to wa ninu ẹni naa wo, wọn si ri i pe oku ọmọdebinrin kan ti wọn ti ge ọwọ rẹ mejeeji kuro ni.''

Agbẹnusọ ọlọpaa sọ pe afurasi naa sọ pe oun ko mọ nnkan kan nipa bi ọwọ mejeeji ṣe kuro lara oku, o ni baba ọmọ to ku, Sunday Adegboyega, tawọn jọ n gbele loun fẹẹ ba sin oku ọmọ rẹ sibi to jinna sile awọn.

Ṣugbọn nigba to gbe oku naa kuro nile baba rẹ, gbogbo ara ọmọ naa perepere.

Alukoro ọlọpaa Ogun tẹsiwaju, pe Ogidan Mustapha yoo ni lati ṣalaye ohun to sọ ẹya ara oloogbe Oriyomi di ohun ti ko pe mọ.

O fi kun un pe ọlọpaa tun mu awọn eeyan mẹta kan naa ti wọn ran Ogidan lọwọ lati gbẹ ilẹ ti wọn ju oku naa si lẹba odo

Ọjọ́bọ ni iná mọ̀nàmọ́ná pa Oriyọmi, ọjọ́ Ẹtì ni ẹ̀yà ara rẹ̀ di àwátì

Ninu alaye ti Peace Adegboyega ti i ṣe Iya Oriyomi, ṣe fun awọn ọlọpaa, o sọ pe ina mọnamọna lo gbe ọmọ oun l’Ọjọbọ, ọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹsan-an ọdun 2024.

Nnkan bii aago mẹwaa kọja ogun iṣẹju lo ni iṣẹlẹ aburu naa ṣẹlẹ si Oriyomi lọjọ naa, eyi to pada yọri si iku ọmọdebinrin naa.

Iya Oriyomi ṣalaye pe bi awọn yoo ṣe sinku ọmọ oun lawọn n ṣeto.

O ni o ya oun lẹnu bi oku ṣe de ọwọ Ogidan, ti ẹya ara rẹ ko si pe mọ.