'Mo ṣàìsàn, díẹ̀ ló kù kí orí mi yí lẹ́yìn fíìmù Amina Eleha tí mo ṣe'

Oríṣun àwòrán, Amina Eleha/Instagram
Agba oṣerebinrin, Adebukola Mosoba, ti ọpọ eeyan mọ si Amina Eleha ti ṣalaye ohun ti oju rẹ ri lẹyin to kopa pataki ninu fiimu Amina Eleha.
Agba oṣere naa sọrọ yii ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu Biola Adebayo, t'oun naa jẹ oṣere.
Arabinrin Mosoba ni Jide Kosoko lo pe gbogbo awọn oṣere to kopa ninu ere Amina Eleha.
"Ọmọba Kosoko lo sọ pe emi ni mo maa ṣe Amina Eleha gan an ninu ere naa."
Agba oṣere naa ni ọjọ idunnu ni ọjọ naa jẹ fun oun, "ṣugbọn o tun jẹ idunnu idakeji nitori awọn musulumi foju mi ri mabo".
O ni wọn fi ẹsun kan pe Amina Eleha ti a ṣe jẹ iyawo Anabi, ti sinima naa si jẹ ọna lati ba ẹsin jẹ.
"Oju mi ma ri mabo, o kudiẹ ki ori ọta mi yi ti kii ba ṣe pe mo ni baba ati iya ti mo lọ sa ba nilu oke pe nnkan bayii n ṣe mi.
Lootọọ ọba ni baba mi, ṣugbọn musulumi ni i ṣe.
Baba ati Iya mi lo ṣa ṣe itọju mi."
Arabinrin naa sọ pe ere Amina Eleha sọ oun di ilumọọka, "ṣugbọn awọn ẹlẹṣin musulumi ni a gbọdọ ṣe atunṣe ere naa.
Iṣẹ yẹn gan an ko tii jade rara ti wọn ti bẹrẹ si ni gbogun ti mi lẹyin ti wọn gbọ ipolowo ere naa.
Wọn ni awọn o nii gba tori Amina Eleha ju ọkọ rẹ silẹ lati oke ninu ere ọhun.
Nigba t'awọn eeyan bẹrẹ si ni maa wo ere naa ni wọn sọ pe ki a parọ akọle ere naa lati Amina Eleha si Afomọ.
Mo maa n gbọ ohun wi pe maa ku - Amina Eleha
Nigba to ya ni ogun tun dide si mi nibi iṣẹ tiata ti awọn ọmọ to n ba mi ṣiṣẹ gbe miliọnu meji owo fiimu mi lọ.
Nigba to di aarin kan ni wọn tun pe mi ṣiṣẹ tiata kan nibi ti ẹnikan ti sọ fun mi pe ologo atijọ ni mi.
Ọrọ naa dun mi debi wi pe mo sunkun gan an tori ọrọ naa pami lẹkun pupọ.
Koda, wọn jokoo le fiimu naa nitori mo kopa ninu rẹ.
Lẹyin naa ni mo ṣe aisan debi wi pe mi o le jẹun fun oṣu mẹta, ti mi o si le dide duro.
Mo maa n gbọ ohun wi pe maa ku, ṣugbọn mo maa n da a pada pe mi o ni ku.
Wọn gbe mi de ile iwosan ṣugbọn wọn o ri nkan to n ṣe mi.
Aisan naa ṣakoba fun ọpọlọ mi, ti wọn ba n pe "a", emi maa pe "b", mi o tiẹ tun wa riran mọ gan an lasiko naa.
Lẹyin naa ni wọn ni ki a lọ fi ẹsẹ ile tọọ.
Ṣugbọn ẹni ti Ọlọrun ko ba pa, eeyan ko le pa a.
'Baba ko fẹ ki n ṣiṣẹ tiata"
Amina Eleha ni nigba ti wọn yẹ akọsẹjaye oun wo ni wọn sọ pe aburo baba oun lo gbọdọ tọ oun dagba.
Agba oṣere naa ṣalaye pe gẹgẹ bi ẹni ti wọn bi si ile ọba, o di dandan ki wọn yẹ akọsẹjaye gbogbo ọmọ ti wọn ba wo, kii ba jẹ musulumi tabi ẹlẹsin Kristẹni.
Lati igba ti mo ti wa nile ẹkọ alakọbẹrẹ ni mo ti bẹrẹ iṣẹ tiata niluu Eko.
Koda, bi a ti n kọ iṣẹ tiata nigba naa ni a tun n kọ ẹṣẹ jija.
Awọn oṣere bii Madam Sajẹ ati Baba Suwe to ti dero ọrun lonii ni a jọ kọ ẹṣẹ jija.
Baba ko kọkọ gba ki n ṣiṣẹ tiata tori o ni ọmọ ọba ni mi, ati pe ọmọ ọba kii ṣẹru.
Baba mi sọ pe iṣẹ ẹru n'isẹ tiata."















