Taa ni yóò gba ipò gómìnà lọ́wọ́ Obaseki ní Edo?

Ọjọ Abamẹta, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan-an, ni idibo gomina yoo waye nipinlẹ Edo, nibi ti oludije mejidinlogun yoo ti kopa.
Eyi n waye nitori bi Gomina Godwin Obaseki ṣe n pari saa rẹ keji gẹgẹ bi gomina ipinlẹ naa.
Eeyan 2,629,025 lo ti forukọ silẹ lati dibo ni gbogbo ijọba ibilẹ mejidinlogun , ati ibudo idibo 4,519, to wa ni ipinlẹ Edo.
Taa wa a ni yoo gba ipo lọwọ Obaseki?
Idi re e ti a fi ṣe akojọpọ diẹ lara nnkan to yẹ ki o mọ nipa awọn oludije gboogi mẹta.
Asuerinme Ighodalo (PDP)
Asuerinme Ighodalo ni oludije fun ẹgbẹ osẹlu Peoples Democratic Party, ẹgbẹ to n ṣe ijọba lọwọ nipinlẹ naa.
Onimọ nipa ọrọ aje, agbẹjọro ati oloṣelu ni Ighodalo.
Wọn bi i ni oṣu Keje, ọdun 1959 ni abule Okaigben, nijọba ibilẹ Esan South, nipinlẹ naa.
Ẹni ọdun mẹrinlelọgọta naa ni iriri nidi iṣẹ karakata ipin idokowo, to fi mọ awọn ofin to rọ mọ okoowo ṣiṣe.
Asue, gẹgẹ bi orukọ ti ọpọ eeyan mọ ọ si nipinlẹ Edo, ti jẹ Alaga Sile ifowopamọ Sterling.
Bakan naa lo wa ninu igbimọ ọrọ aje labẹ iṣakoso gomina ipinlẹ naa nigba kan, Adams Oshiomole, ati gomina to w anibẹ bayii, Godwin Obaseki.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC, Asue sọ pe ọrọ aje ni oun yoo mojuto julọ.
Ighodalo ni atilẹyin Gomina Obaseki, eyi ti ọpọ gbagbọ pe oun lo jẹ ko bori igbakeji gomina ipinlẹ naa, Philip Shuaibu, ninu idibo abẹle ẹgbẹ wọn, ṣugbọn Ọgbẹni Igbodalo sọ pe oun ko ni baba ninu osẹlu.
Monday Okpebholo (APC)
Oludije mọkanla ni Monday Okpebholo bori nigba to ni ibo 12,433 ninu idibo abẹle ẹgbẹ osẹlu rẹ.
Oloṣelu ni Okpebolo – Wọn bii ni ọdun 1970, ni abule Uromi, nijọba ibilẹ Esan.
Ibẹ lo si ti bẹrẹ owo ṣiṣe ko to o di oloṣelu.
Lọwọlọwọ, ẹni ọdun mẹtalelaadọta ọhun ni sẹnetọ to n ṣoju Edo Central nile igbimọ aṣofin agba.
O si ri atilẹyin gomina tẹlẹ, to tun jẹ alaga ẹgbẹ APC nigba kan, Adams Oshiomole, eyi to mu ki ọpọ gbagbọ pe idibo gomina yoo ṣẹnu’re fun.
Olumide Akpata (LP)
Ọdun 1972 ni wọn bi Olumide Akpata.
Ṣaaju ko to di oloṣelu, agbẹjọro to da n tọ ni, o si ti fi igba kan jẹ aarẹ ẹgbẹ awọn agbẹjọro ni Naijiria.
Ọdun 1993 lo bẹrẹ iṣẹ agbẹjọro, to si da ileeṣẹ ofin tiẹ silẹ, Templars, lẹyin ọpọlọpọ ọdun to ti n ṣiṣẹ.












