'Kí ìyà má ba à jẹ èmi àti àbúrò mi ló mú kí n máa bá àwọn èèyàn gbé oyún'

Àkọlé fídíò, 'Mi ò fẹ́ kí ìyà tó jẹ́ ìyá mi jẹ́ èmi àti àbúrò mi ló mú kí n máa bá àwọn èèyàn gbé oyún'
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Idunnu ọpọ tọkọtaya ni pe lẹyin igbeyawo, ki wọn o ri ọmọ wọn gbe jo.

Ṣugbọn nigba miran, ọrọ kii ri bẹẹ, eyi to ma n waye nitori oriṣiriṣi nnkan to le fa airọmọbi fun tọkọtaya to wu lati bimọ.

Ni aye igba kan, ko fi bẹẹ si ọna abayọ si iṣoro airọmọbi ju pe ki tọkọtaya kun fun adura, gba itọju nileewosan tabi ni ilana ibilẹ. Awọn miran si ma n gba ọmọ ọlọmọ tọ, eyi ti wọn n pe ni ‘Adoption’ ni ede Gẹẹsi.

Amọ lasiko yii, paapaa lati bi ọdun melo kan, ilana iranlọwọ kan fun ọmọ bibi ti awọn eeyan tun n lo ni ki ẹlomiran ba wọn gbe oyun ọmọ wọn.

Ilana yii ni wọn n pe ni ‘Surrogacy’’.

Awọn onimọ iṣegun oinbo ma n fi ilana surrogacy lọ awọn obinrin to n woju Ọlọrun fun ọmọ, paapaa awọn ti ile ọmọ wọn ba ni ailera kan, eyi to mu ko nira fun wọn lati gbe oyun si ikun wọn.

Ẹlomiran naa tun le lo surrogacy boya nitori ko wu u lati gbe oyun si ikun, tabi ẹlomii to ni ailera ti ko le jẹ ko ni agbara lati gbe oyun.

Nitori imọ ijinlẹ tuntun yii, awọn ileeṣẹ kan wa to ma n ṣawari awọn obinrin to le ba obinrin akẹẹgbẹ wọn gbe oyun, ti awọn naa yoo si gba owo iṣẹ wọn.

Kaakiri agbaye ni wọn ti n ṣe surrogacy, eyi ti ko yọ orilẹ-ede Naijiria silẹ.

BBC Yoruba ba meji sọrọ lara awọn obinrin to n fi biba awọn idile ti ko ri ọmọ bi, gbe oyun ọmọ wọn, sọrọ.

Wọn sọ nipa nnkan to gbe wọn de idi iṣẹ naa, ati awọn anfaani ti wọn n ri.

Obinrin to loyun

Oríṣun àwòrán, Others

Ohun to gbe Ajokeade ati Abebi de idi iṣẹ Alagbabi

Ajokeade ati abebi, obinrin meji to n ṣe iṣẹ Alagbabi
Àkọlé àwòrán, Nitori atijẹ ni Ajokeade ati Abebi fi n ṣe iṣẹ Alagbabi
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹni ọdun mkanlelọgbọn, Lola Ajokeade, ti bi ọmọ meji rii, ko to o bẹrẹ iṣẹ biba awọn obinrin bi tiẹ gbe oyun.

Ajokeade ti ṣe igbeyawo ri, amọ nigba ti igbeyawo naa tuka, ti ko si ri owo lati maa da gbọ bukata awọn ọmọ rẹ mejeeji, lo mu ko di Alagbabi.

O ni ninu riinajo oun, ni oun ti ṣakiyesi pe ọpọlọpọ lo wu lati jẹ ọlọmọ laye, amọ ti ko ni oore-ọfẹ.

“Emi ti Ọlọrun yọnda fun, mi o ri owo fi tọ wọn. Nnkan to jẹ ki n pinnu niyẹn pe ọna re e lati fi ayọ ati idunnu si aye awọn ẹlomiran.”

Obinrin keji, ti ko darukọ rẹ, amọ ti a o pe ni Abebi, sọ pe oun di Alagbabi fun anfaani oun, iya, aburo ati ọmọ oun.

Gẹgẹ bi ọrọ ti Abebi, ọmọ mẹrinlelogun ni baba rẹ bi, amọ baba naa jẹ ẹni ti kii tọju ọmọ, eyi to sọ itọju awọn ọmọ naa di ti iya onikaluku wọn.

“Mo pinnu pe iya to jẹ iya mi, ko tun gbọdọ jẹ emi naa ati awọn aburo mi ni idi ti mo fi ṣe surrogate mother.”

Ẹnikan ṣoṣo to jẹ ẹgbọn fun Ajokeade lo mọ pe o n ṣe iṣẹ Alagbabi.

Fun Abebi ni tiẹ, o ni oun ko sọ iru iṣẹ ti oun n ṣe fun awọn ọrẹ oun nitori pupọ eeyan gbagbọ pe ẹni to jẹ alagbabi n ta ọmọ inu wọn ni.

Amọ iya ati ẹgbọn rẹ mọ pe o n ṣe e .

O ni oun el gba awọn eeyan ni imọran lati ṣe iṣẹ naa, nitori pe o san ju ṣiṣe iṣẹ idọti tabi isẹ aṣẹwo.

Abebi ni tiẹ sọ pe ọtọ ni eero ti oun ni nipa biba eniyan gbe oyun, amọ nnkan ti oun ba yatọ nigba ti oun bẹrẹ rẹ.

“Ọkan mi balẹ ninu iṣẹ yii ju igba ti mo n ṣe awọn iṣẹ bii irun didi, iṣẹ oṣu ati ọmọọdọ.

“Mi o ri ere, ati ifọkanbalẹ ninu awọn iṣẹ ti mo ti ṣe bi eyi ti mo n ri nidii iṣẹ Alagbabi ti mo wa a ṣe.”

Oludasilẹ ileeṣẹ to n sẹto bi awọn obinrin ṣe n ba ẹlomii gbe oyun, Meet surrogate Mothers, Arabinrin Olaronke Thaddeus, sọ pe ni kete ti wọn ba ti fi ẹyin to ti di ọmọ sinu Alagbabi, awọn ma n jẹ ki wọn o wa ni amojuto awọn fun awọn ọsẹ diẹ, “ki wọn o ma lọ gbe oyun ti kii ṣe ti awọn onibara wa fun wọn”.

Asiko naa ni wọn tun ma n fun wọn ni idanilẹkọọ, ati fifi ọwọ si iwe adehun iṣẹ.