Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa àìsàn Encephalopathy tó ń bá Bisola Badmus fínra

Oríṣun àwòrán, Bisola Badmus/Instagram
Laipẹ yii ni gbajumọ oṣerebinrin, Bisola Badmus, ke gbajare nipa aisan kan to n ṣe e.
Bisola ni o ti to ọdun meji bayii ti aisan naa ti n ba oun finra, ti ko si ni anfaani lati ri iṣẹ kankan gba lati igba naa.
Ni ọdun 2023, lọjọ ibi rẹ ni Bisola Badmus, ninu atẹjade kan to fi sori ayelujara Instagram rẹ ti kọkọ kede pe oun ni aisan Encephalopathy.
Kí ni a n pe aisan Encephalopathy?
Encephalopathy tumọ si aisan kan to ma n ṣe ọpọlọ. Eyi ma n mu ayipada ba bi ọpọlọ eeyan ṣe ri tabi bi ara ṣe n siṣẹ pẹlu ọpọlọ.
O fẹ fara jọ aarun ọpọlọ nitori o ma n da ọpọlọ ru, ti iwa eeyan si ma n ṣe segesege.
Encephalopathy kii ṣe aisan ẹyọ kan lasan sugbọn apapọ awọn aisan to buru gan-an ni.
Aisan naa lewu pupọ si agọ ara, ti eeyan ko ba tete ri itọju gba, o ṣeese ko fa aisan ọpọlọ.
Ọpọ awọn eeyan ma n da Encephalopathy ati Encephalitis papọ sugbọn wọn kii se nnkankan naa.
Encephalitis ni aisan to ma n kọlu ọpọlọ, eyi ti yoo mu ọpọlọ naa wu soke.
Orisirisi meji aisan Encephalopathy lo wa: Reversible (eyi to ṣe e tọju) ati irreversible (eyi ti ko ṣe e tọju).
Awọn ohun to le fa Encephalopathy
Hepatic Encephalopathy: Eyi ma n waye nigba ti ẹdọ ba ni iṣoro, ti ko si le yọ idọti kuro ninu ẹjẹ bi o ṣe yẹ. Awọn idọti naa yoo ṣarajọ ninu ara, ti eyi si le fa iṣoro.
Metabolic Encephalopathy: Eyi ma n waye nigba ti aisan mii bi aisan kindinrin ba wa ninu ara, eyi si ma n se akoba fun ọpọlọ lati ṣiṣẹ.
Aarun ọpọlọ, bi Encephalitis tabi meningitis naa le se akoba fun ọpọlọ.
Fun irreversible Encephalopathy - eyi ti ko ṣe e tọju:
Chronic traumatic Encephalopathy: Eyi ma n waye latari fifi ori pa, ti o si se akoba fun ọpọlọ.
Hypoxic-ischemic Encephalopathy: Eyi ma n waye nigba ti ọpọlọ ko ba ri atẹgun to peye gba. Eyi le fa giri fun eeyan.
Ki ni apẹẹrẹ aisan yii?
- Pi padanu oye
- Igbagbe
- Iyatọ ninu iwa ẹda
- Isoro lati ronu
- Isoro oju
- Airi oorun sun
- Aile sọrọ dada
- Giri
Itọju aisan Encephalopathy
Gẹgẹ bi oju opo ayelujara ileeṣẹ eto ilera United Kingdom ṣe sọ, aisan Encephalopathy ko ni iwosan, amọ wn le mojuto awọn apẹẹrẹ rẹ.
Lara itọju ti wọn ma n fun iru awọn eeyan to ba ni aisan yii farajọ eyi ti wọn ma n fun awọn to ba ni aisan igbagbe, dementia.
Oogun lilo ati awọn vitamin kan naa wa lara itju
Amojuto awọn aisan tabi aarun mii to ba wa ninu ara
Iranlọwọ fun ọrọ sisọ (speech therapy)
Iranlọwọ fun iṣẹ ọpọlọ (cognitive behavioural therapy)
Ati bẹẹbẹẹ lọ.












