Àwọn àǹfàání tí gbígbàgbé nǹkan le ṣe fún ìgbéayé rẹ

Àwòrán obinrin to fọwọ di ori mu pẹlu ironu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Igbagbe o loogun, ko si sẹni kan laye yii ti ko le gbagbe nnkan.

Ṣugbọn ki i wu eeyan lati jẹ onigbagbe, nitori ipalara ti igbagbe ọhun le mu wa.

Lati waa fi han pe oore n bẹ ninu ibi, pe anfaani wa lara ki eeyan gbagbe nnkan nigba mii, iroyin yii ṣatupalẹ awọn oore to wa ninu igbagbe.

Gẹgẹ bi onimọ nipa irori ẹda, Ọjọgbọn Charan Ranganath, ṣe ṣalaye ninu iwe rẹ tuntun to kọ, o ni igbagbe maa n mu ọkan eeyan fuyẹ.

Onimọ ijinlẹ yii sọ pe bi ọpọlọ eeyan ṣe maa n ranti ohun to ti kọja ni i ṣe pẹlu irori eeyan, ati bo ṣe woye awọn eeyan yooku si, pẹlu oju ti eeyan fi n wo ile aye funra rẹ gan-an.

Ọjọgbọn Ranganath, ẹni to ti lo ọgbọn ọdun nipa wiwo iṣesi ati irori awọn eeyan, sọ pe awọn akọsilẹ to wa nipa igbagbe ko fi bẹẹ jẹ otitọ.

O ṣalaye fun David Robson, akọroyin lẹka imọ sayẹnsi, nipa bi eeyan ṣe le ni imọ kikun nipa iranti, ti wọn yoo si tibẹ ni alaafia ọkan.

Ànfààní wo ló wà nínú kí èèyàn gbàgbé nǹkan?

Nigba to n fi apẹẹrẹ gbe ọrọ rẹ lẹsẹ, Ọjọgbọn Ranganath, sọ pe 'ti mo ba gba yara kan ni ile itura lonii, bi mo ba tun wa n ranti nọmba yara naa lẹyin ọsẹ meji ti mo lo nibẹ, tabi ti mo n ranti oju gbogbo eeyan ti mo ba pade loju ọna mi, mi o ro pe eyi yoo ṣe anfaani kankan fun ara mi.

‘’Ṣe o yẹ ki n maa gbe oju awọn eeyan ti mo ba pade sọkan ni, ki n maa ranti wọn nigba ti ko si kinni kan to da wa pọ mọ?

Airanti wọn yoo mu ọkan mi fuyẹ.

Kí ló dé tí àwọn èèyàn máa ń gbàgbé nńkan bí wọ́n ṣe ń dàgbà sí i?

'Ohun to wa nibẹ ni pe bi a ṣe n dagba si i ni ọjọ n lọ lorii wa si i.

Eyi ko tumọ si pe a ko le gbe nnkan sinu ọpọlọ wa mọ ka si mọ ọn lori, ṣugbọn nitori a ko f’ọkan si ohun to yẹ ka maa ranti ni.

Ọpọlọpọ nnkan ti ko ṣe pataki lo maa n dari ọkan eeyan sibo miran nigba mii.

Awọn nnkan wọnyii yoo gbe ọkan wa kuro nibi ohun to ṣe pataki fun wa to si yẹ ka mojuto.

Fun idi eyi, nigba ti a ba nilo ohun to ṣe pataki ti a ko gbe sọkan, a ko ni i ranti rẹ mọ nigba ti a nilo rẹ yẹn.

Ọ̀nà wo la lè gbà láti ṣẹ́gun èyí, tí yóò sì mú ọpọlọ jí pépé

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọna mẹta ni ọna abayọ to wa.

Akọkọ ni pe awọn ohun ti a n gbe si ọpọlọ maa n figa gbaga lati gba ọkan wa.

Ṣugbọn ohun ti eeyan ba n gbe sọkan ju, tabi to n tẹnu mọ ju ni yoo maa wa nipo akọkọ ninu ọpọlọ rẹ. Ko ni i gbagbe .

Awọn iranti eeyan, aworan pataki, bi ẹnikan ṣe maa n ṣe tabi sọrọ, ki i kuro ni irori eeyan.

Bi a ba f’ọkan si awọn nnkan kan to ti mọ wa lara tabi ti a maa n gbọ, o maa n jẹ ki eeyan ranti nnkan daadaa.

Ọna keji ni pinpin ohun ti a fẹẹ ranti si ipele ipele.

Bi nnkan ba ṣe nitumọ si fun eeyan ni yoo ṣe to wọn si iranti rẹ si.

Ọna kẹta ni pe eeyan ṣe agbekalẹ ilana kan lati maa ranti nnkan kan.

O le ṣoro lati maa wa ohun ti yoo jẹ iranti, niṣe lo yẹ ki eeyan ṣe ami kan ti yoo jẹ ko maa ranti ohun ti ko fẹẹ gbagbe.

Bi apẹẹrẹ, orin kan le wa ti yoo maa ran eeyan leti nnkan kan lasiko kan laye ẹni. Awọn nnkan mi-in naa si wa ti eeyan le lo lati maa fi ranti ohun ti ko fẹẹ gbagbe.

Bi n ko ba fẹẹ gbagbe lati gbe ike ti mo n da idọti sinu rẹ nu lọjọ ti awọn akolẹ ba de, mo ti le gbe ike naa si ẹba ọna ṣaaju igba ti wọn yoo de.

Bẹẹ ni n o si ti maa ro o lọkan mi pe mo fẹẹ da ilẹ yii nu.

Bi mo ba ti n de ẹnu ọna ti mo n ri ike ọhun, yoo maa ran mi leti ohun ti mo fẹẹ ṣe.

Èrò ọkàn wa máa ń tako ohun tí a gbé sórí nígbà míì

Bi o ba ri baba tabi iya rẹ ti o ti ri tipẹ, ti o si ṣakiyesi pe oju obi naa ti yi pada si ohun ti iwọ mọ tẹlẹ, nnkan kan lo fa a.

Ẹsẹkẹsẹ ti o ti ri ayipada yii naa lo ti gbọdọ gbiyanju lati ranti bi oju obi rẹ ṣe ri tẹlẹ, ti iwọ yoo si maa ro nipa ayipada ti o ṣakiyesi.

Nigba mi-in, ero ọkan wa maa n tako ohun ti a gbe sori, ti a si ti mọ tọkan-tọkan.