Mọ̀ nípa ohun tó máa ń fa àárẹ̀ lásìkò ìrìnàjò àti ìdènà rẹ̀

Obìnrin tí àárẹ̀ ọkọ̀ ń dààmú

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Ghada Nassef
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Fún àwọn kan, ní kété tí wọ́n bá ti fẹ́ ṣe ìrìnàjò yálà pẹ̀lú ọkọ̀ òfurufú, ọkọ̀ ojú irin tàbí ọkọ̀ orí ilẹ̀ ni wọ́n máa ń wà ní inú fu àyà fu.

Ìrònú ara wọn tí kìí yá tí wan bá wà nínú ọkọ̀ ló máa ń gba ọkàn wọn ju nǹkan tí wọ́n fẹ́ lọ ṣe níbi tí wọ́n ń lọ lọ.

Àárẹ̀ ìrìnàjò máa ń wáyé nígbà tí ọpọlọ èèyàn bá ń gba oríṣiríṣi àmì – láti nǹkan tí ojú wa ń rí ni àti nǹkan tí ara wa ń sọ ni lásìkò ìrìnàjò.

Bí àpẹẹrẹ, tí èèyàn bá wà nínú ọkọ̀ tó ń lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ara èèyàn kò kúrò ní ojú kan àmọ́ ojú wa ń rí àwọn nǹkan tó wà ní àyíká.

Àwọn tí wọ́n máa ń ṣe àárẹ̀ lásìkò ìrìnàjò jẹ́ àwọn tí ara wọn máa ń dáhùn sáwọn nǹkan tó ń lọ ní àyíká wọn lásìkò tí ọkọ̀ wọn bá wà lórí ìrìn, tó sì máa ń fa kí èébí máa gbé wọn, òyì kíkọ́ àti kí wọ́n ṣà wà nínú ìnira.

Kódà, ẹlòmíràn tí àwọn nǹkan yìí sábà máa ń ṣe máa ń wá gbogbo ọ̀nà láti dènà lílọ fún ìrìnàjò pàápàá èyí tó bá gùn.

Kí ló máa ń fa ìrora lásìkò tí èèyàn bá wà nínú ọkọ̀ àti pé kí ni ìtọ́jú rẹ̀?

Kí ló máa ń fa àárẹ̀ lásìkò ìrìnàjò?

Àwòrán vestibular system

Láti le ní ìmọ̀ kíkún lórí nǹkan tó máa ń fa àárẹ̀ lásìkò tí èèyàn bá ń ṣe ìrìnàjò, ó yẹ ká mọ bí ọpọlọ wá ṣe máa ń ṣàmúlò àwọn ẹ̀yà ara tí a fi ń mí, ríran àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ọpọlọ máa ń gba àmì láti inú àti inú ara lóòrè kóòrè.

Inú etí wà lára àwọn ẹ̀yà ara tí wọ́n ń pè ní “vestibular system”. Vestibular system jẹ́ àkójọpọ̀ nǹkan tí wọ́n ń pè ní “Semi-circular canals” àti “saccule àti utricle”. Àwọn ẹ̀yà ara yìí ló máa ń fún ọpọlọ ní ìròyìn nípa bí ara bá ṣe ń yí.

Semi-circular canals ló gbé omi kan tó máa ń yí nígbà tí a bá yí orí wa ró. Àwọn ló máa ń sọ ibi tí orí bá yí sí fún ọpọlọ.

Saccule àti utricle ló máa ń sọ fún ọpọlọ bí èèyàn bá fò sókè, sún síwájú tàbí lọ sẹ́yìn.

Àmọ́ tí ojú bá rí nǹkan, tí ara gbúròó nǹkan mìíràn, tí nǹkan tí inú etí gbọ́ yàtọ̀ pátápátá, tí ọpọlọ ń gba ìròyìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló máa ń fà àárẹ̀ lásìkò ìrìnàjò.

Àwọn nǹkan yìí ló máa ń fa kí èébì máa gbé èèyàn, orí fífọ́ àti kí ara máa ni èèyàn.

Kí ni àwọn àmì àpẹẹrẹ àárẹ̀ Ìrìnàjò?

Onírúurú àìlera ni àárẹ̀ ìrìnàjò máa ń mú dání.

Wọ́n máa ń bẹ̀rẹ̀ díẹ̀ díẹ̀ tí yóò sì máa pọ̀ si bí ìrìnàjò bá ṣe ń pẹ́ sí.

Lára wọn ni:

  • Òyì
  • Èébì
  • Orí fífọ́
  • Àágùn
  • Kí ara funfun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ

Ó máa ń tó ogún ìṣẹ́jú lẹ́yìn tí ìrìnàjò bá parí kí àwọn nǹkan tó yé ṣe èèyàn mọ́, tí èyí tó bá pọ̀ sì máa ń tó odidi ọjọ́ kan.

Ta ni ó lè ní àárẹ̀ ìrìnàjò?

Ọmọdé tí àárẹ̀ ìrìnàjò ń ṣe nínú ọkọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kò sí ẹni tí àárẹ̀ ìrìnàjò kò lè ṣe ṣùgbọ́n àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún méjì sí méjìlá, àwọn aláboyún, àti àwọn tí ẹ̀fọ́rí máa ń dà láàmú ló sábà máa ń ṣe jùlọ.

Ohun tó yani lẹ́nu ni pé àwọn ọmọ ọwọ́ kìí sábà ṣe àárẹ̀ yìí. Ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìmọ̀ ọpọlọ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Westminster, London, John Golding ní ó ṣeéṣe kí èyí rí bẹ́ẹ̀ látàrí pé ọpọlọ wọn kò ì tíì dàgbà tó láti ní ìmọ̀ nípa ìrìnàjò.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Golding ní àárẹ̀ yìí tún máa ń jẹ́ àjogúnbá. Ó ní ìdá márùndínláàdọ́rin àwọn èèyàn tó máa ń dà láàmú ló jẹ́ pé wọ́n jogún rẹ̀ ni.

Báwo ni àdínkù ṣe le bá a?

Yorùbá ní ó ń bọ̀, ó ń bọ̀, àwọ̀n là á dẹ dè é.

Àwọn nǹkan tó lè ṣe ìrànlọ́wọ́ láti dènà àárẹ̀ lásìkò ìrìnàjò nìyí:

Ṣáájú ìrìnàjò:

  • Yàgò fún jíjẹ oúnjẹ tó wúwo àti oúnjẹ tó bá lára
  • Dín ọtí mímu kù
  • Sùn dáadáa

Lásìkò ìrìnàjò:

  • Má kàn jókòó sí ibikíbi: jókòó síwájú ọkọ̀ tó bá jẹ́ pé ìrìnàjò orí ilẹ̀ ni, jókòó sí àárín tó bá jẹ́ pé ọkọ̀ ojú omi tàbí ọkọ̀ ojú irin kí ó sì mú ààyè tí fèrèsé rẹ̀ bá kọjú síwájú.
  • Ṣọ́ra fún yíyí orí lójijì
  • Tí ààyè bá wà fún ọ, ṣí fèrèsé kí atẹ́gùn máa wọ inú ọkọ̀
  • Má ka ìwé, wò fíìmù tàbí ló ẹ̀rọ kankan
  • Fi nǹkan bíi gbígbọ́ orin máa gbé ọkàn rẹ kúrò
  • Di ojú rẹ
  • Mu ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi

Atalẹ̀

Tíì tí wọ́n fi atalẹ̀ ṣe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àwọn ìwádìí kan sọ pé atalẹ̀, bí èèyàn bá jẹ ẹ́ tàbí fi sínú tíì, máa ń dín èébì tàbí òyì kù.

Àmọ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n Golding ní ìwádìí náà ṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí èyí.

Ó ṣàlàyé pé kìí ṣe àárẹ̀ ìrìnàjò ni atalẹ̀ yóò dínkù bíkòṣe ọ̀nà ọ̀fun ni ó ń ṣiṣẹ́ fún

Ṣíṣe àmójútó èémí

Ṣíṣe àmójútó èémí túmọ̀ sí ríri dájú pé èèyàn ń mí bó ṣe yẹ.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Golding ní ipa ṣíṣe àmójútó èémí lára dàbí ìgbà tí èèyàn ti lo ìdajì oògùn tó ń dènà àárẹ̀ lásìkò ìrìnàjò.

Ó ní mímí máa ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọpọlọ tí kò sí jẹ́ kí èèyàn máa gbúròó pé ó fẹ́ ṣe àárẹ̀.

Oògùn lílò

Àwọn oògùn tó ń dènà àárẹ̀ lásìkò kìí ṣe pé wọ́n máa ń tán àárẹ̀ náà bíkòṣe pé wọ́n máa ń dènà àwọn ìnira tí èèyàn máa ń ní lásìkò ìrìnàjò.

Nítorí náà èèyàn gbọ́dọ̀ ti lò wọ́n ṣáájú - bíi ọgbọ̀n ìṣẹ́jú sí wákàtí kan tí ìrìnàjò máa bẹ̀rẹ̀ láti lè ri pé wọ́n wọnú ẹ̀jẹ̀.

Fún àwọn oògùn tí wọ́n máa ń lẹ̀ mọ́ ara, òhun máa ń pẹ́ kó tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nítorí inú awọ ara ló máa ń gbà ṣiṣẹ́. Tó bá ku wákàtí mẹ́wàá tí ìrìnàjò yóò bẹ̀rẹ̀ ló yẹ fún lílò.

Àjọ tó ń rí sí ètò ìlera ní orílẹ̀ èdè United Kingdom, UK ní àgbàlagbà àti ọmọdé tí ọjọ́ orí rẹ̀ bá ti lé ní ọdún mẹ́wàá ló lè lò ó.

Kí ni ìyàtọ̀ àárẹ̀ ìrìnàjò àti vertigo?

Obìnrin tí vertigo ń yọ lẹ́nu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àwọn èèyàn sábà máa ń ṣi àárẹ̀ ìrìnàjò mú sí vertigo nítorí méjèèjì máa ń fa èébì àti òyì ojú.

Àmọ́ ìyàtọ̀ wà láàárín àwọn àìsàn yìí:

  • Vertigo le ṣe èèyàn láì kí ṣe wí pé ẹni náà wà nínú ọkọ̀ tó ń rìn. Kódà ó lè ṣe èèyàn lórí ìdùbúlẹ̀
  • Vertigo máa ń jẹ́ kó dàbí pé nǹkan ń yí nígbàkígbà tí èèyàn bá yí orí
  • Ìṣẹ́jú àáyá ni vertigo fi máa ń ṣe èèyàn
  • Àwọn tó bá ti dàgbà ni vertigo máa ń sábà ṣe

Ó máa ń dára kí èèyàn gbáradì láti ṣe àmójútó àárẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ kí ó tó ṣe ìrìnàjò.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn tí àárẹ̀ yìí máa ń dà láàmú ṣe máa ń sọ, má fi ààyè gbà á láti sọ bí wà á ṣe lo ìgbésí ayé rẹ fún ọ.