Èèyàn 129 kú, 60 míì farapa lásìkò tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n ń gbìyànjú láti sálọ

DR Congo jailbreak

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ijọba Democratic Republic of Congo ti sọ pe eeyan mọkandinlaadọfa ti jade laye lẹyin ti awọn ẹlẹwọn kan gbiyanjuu lati salọ niluu Kinshasha.

Minisita fun ọrọ abẹle, Jacquemain Shabani sọ pe ọta ibọn lo pa ẹlẹwọn merinlelogun nigba ti awọn to n sọ ọgba ẹwọn naa n yinbọ soke.

O ni ọpọ awọn mii lo ku latari bi wọn ṣe tẹ wọn mọlẹ pa.

Bo tilẹ jẹ pe iroyin gbode pe ọpọ ẹlẹwọn lo ku nibẹ, ijọba orilẹede naa kọkọ sọ pe eeyan meji pere lo padanu ẹmi wọn.

Lọdun meje sẹyin ni ẹgbẹrun mẹrin ẹlẹwọn sa kurọ lọgba ẹwọn yii kan naa, to jẹ ọgba ẹwọn to tobi julọ lorilẹede ọhun.

Awọn to n gbe lagbegbe ibi ti ọgba ẹwọn naa wa sọ pe awọn gbọ iro ibọn to n dun lakọlakọ ṣugbọn awọn ọlọpaa ko gba ki awọn akọroyin de agbegbe naa.

Daddi Soso, to n gbe lagbegbe ibi ti ọgba ẹwọn ọhun wa sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe “laarin aago mejila si aago kan oru ni iro ibọn n dun lakọlakọ titi di aado marun un idaji.

“Ọpọ eeyan lo ku nibẹ ti awọn kan si salọ. O fi kun pe ṣe lawọn agbofinro n ko oku jade nibẹ.

Awọn fidio kan ti BBC ri amọ ti a ko le fidi rẹ mulẹ ṣafihan ọpọ oku nilẹ, ti awọn mii si n kigbe fun iranlọwọ latari bi wọn ṣe tẹ wọn mọlẹ ti wọn ko si le mi mọ.

Ọgbẹni Shabani ṣalaye nnkan bii ọgọta eeyan lo farapa nibẹ, wọn si ti n gba itọju lọwọ nilẹ iwosan.

Ẹgbẹ awọn ajafẹtọọmọniyan ti ke si awọn ajọ agbaye lati bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Ọgba ẹwọn ọhun ti orukọ rẹ n jẹ Makala ni wọn kọ ni nnkan bii ọdun 1950.

Ileeṣẹ iroyin AFP ni ẹgbẹrun kan abọ eeyan ni ọgba ẹwọ naa le gba amọ ẹgbẹrun mẹrinla ẹlẹwọn lo n gbe nibẹ.