"Ìjọba Tinubu bojú wa jẹ́, ó fojú wa gúngi, nǹkan le koko, wọ́n ní ká fọkàn balẹ̀, a kò rí nǹkan kan"

Àkọlé fídíò, Hike in Petrol Price: Ọ̀pọ̀ aráàlú faraya lórí ìgbé eyé tó le torí ọ̀wọ́n epo
"Ìjọba Tinubu bojú wa jẹ́, ó fojú wa gúngi, nǹkan le koko, wọ́n ní ká fọkàn balẹ̀, a kò rí nǹkan kan"

Ipo ti ọrọ aye Naijiria wa, lo ti n da iporuru ọkan si ọpọ ọmọ Naijira lati igba ti isejọba Bola Ahmed Tinubu ti gori aleefa.

Yatọ si pe ọrọ aje dagun, se ni owo osu wọn, tabi owo to n wọle fun wọn, ko to nnkan.

Bakan naa, ko si ina ọba, ọwọn gogo ounjẹ wa, ti owo epo bẹntirol si n gbowo lori ni ojoojumọ.

Ori eyi ni wọn wa, ti wọn n ba igbe aye wọn yi, ki ọwọn gogo epo bẹntrirol fi gba ilu kan fun odidi ọsẹ mẹsan.

Amọ nigba to di ọjọ Kẹta osu Kẹsan ọdun 2024 ni ajọ elepo rọbi NNPC tun kede pe alekun ti ba owo jala epo bẹntirol kan.

Jala epo naa lo gbera lati N617 lọ si N897 lawọn ileepo NNPC amọ awọn ileepo aladani n tiwọn n ta jala epo laarin N1000 si N1400.

Awọn araalu

Afẹnifere ati ẹgbẹ agbaagba nilẹ Yoruba, YCE ke si Tinubu pe ko da owo epo pada si iye to wa tori ara n ni araalu

Lati igba ti ajọ NNPC ti kede ele owo epo yii ni ọpọ ọmọ Naijiria ti n fi apa janu lori ele owo epo naa.

Yatọ si awọn iwọde ebi n pa wa to ti waye nilẹ Naijiria, awọn oniruuru fidio lo tun n lọ lori ayelujara ninu eyi ti awọn araalu ti n pariwo pe ilu le, ko si owo lode.

Koda, awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ agbasaga bii Afẹnifere ati ẹgbẹ agbaagba nilẹ Yoruba, YCE lo ti ke si aarẹ Tinubu pe ko da owo epo pada si iye to wa tori ara n ni araalu.

Ni ọjọbọ, Ọjọ karun osu Kẹsan ọdun 2024 ni awọn ọlọkada ati oni maruwa gan se iwọde lati tako ọwọn ati ele owo epo.

Tori awọn ọpọ ifapajanu yii to n waye lati ọdọ araalu, lo mu ki BBC Yoruba lọ si igboro lati wadi lọwọ awọn araalu nipa ohun ti wọn n la kọja tori ọwọn epo to n ko ba ọrọ aje wọn.

Bakan naa, a fẹ mọ ipa ti ele to gun epo n ni lori igbe aye wọn ni ojoojumọ.

Awọn to n to fun epo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

"Ìjọba Tinubu bojú wa jẹ́, ó fojú wa gúngi, nǹkan le koko, wọ́n ní ká fọkàn balẹ̀, a kò rí nǹkan kan"

Lasiko ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ, ọpọ araalu ni awọn se isẹ nla lati dibo fun aarẹ Tinubu amọ o ti ba oju awọn jẹ bo se de ori aleefa yii.

“Tinubu ni pe ka l fi ọkan balẹ, a fi ọkan balẹ tan, a ri nnkan kan mọ. O le gan ni.

Ijọba Tinubu da wa, a fi ọkan tan-an. Ijakulẹ la ba pade.

O fi oju wa gun igi, Tinubu ba oju wa jẹ.

Irin ti mo rin ni ana, baba nla mi kankan ko rin iru rẹ ri, se wọn kuku fẹ pa wa yanyan ni, nnkan le gan ni.

Inu ina ọrun apaadi la wa, nnkan ti bajẹ gan ni.

Bi ijọba ko ba sọra, isẹlẹ yii le fa rogbodiyan laarin ilu tori ounjẹ wa meji lojumọ tẹlẹ, a ti ri ẹyọ kan jẹ gan di isẹ nla bayii.

Awọn araalu to n to lati ra epo

Oríṣun àwòrán, Getty Images