Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́ - 6 Owewe, 2024
O di gbere, o darinako, o tun doju ala firi
Lonii ni alagba Micheal Akinkunmi to ya asia Naijiria wọ kaa ilẹ sun niluu Ibadan
Ṣaaju ni wọn kọkọ ṣeto isin ikẹyin fun ni papa iṣere Liberty, to wa lagbegbe Ring Road
Ki wọn to lọ sin oku rẹ sile rẹ to wa lagbegbe Ẹlẹ́bú, nillu Ibadan kan naa
Araalu, mọlẹbi atawọn aṣaaju ẹsin lo peju sibi eto isinku ọhun
Nipinlẹ Ekiti
Gomina Biodun Oyebamiji ti ni awọn oṣiṣẹ ijọba le maa ṣiṣẹ lati ile fun awọn ajọ kan laarin ọsẹ
Amọ o ni ọrọ naa ko kan awọn olukọ, oṣiṣẹ eto ilera kan atawọn agbofinrinro
Nipinlẹ Eko,
Ọwọ ọlọpaa ti tẹ afurasi ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Ayomide Adeleye
Lori ẹsun pe o ṣekupa ọdọbinrin kan, Christiana Idowu lẹyin to kọkọ jii gbe
A gbọ pe ọrẹ ni awọn mejeji, koda ile ijọsin kan ni wọ n lọ, bẹẹ ni wọn tun n tẹle ara wọn lori lori ayelujara