Ìjọba Canada gbé òfin tuntun fáwọn tó bá fẹ́ jápa lọ sí orílẹ̀èdè náà

Oríṣun àwòrán, Marc Miller/Facebook
Ijọba orilẹede Canada ti gbe ofin tuntun kalẹ fawọn akẹkọọ, awọn oṣiṣẹ lati ilẹ okeere at'awọn ọkọ ati aya wọn to ba fẹ lọ si orilẹede naa.
Ijọba Canada ti kede pe oun yoo mi adinku ba iwe aṣẹ lati le ṣiṣẹ fawọn akẹkọọ at'awọn oṣiṣẹ lati ilẹ okeere di ida 35% lọdun 2024 yii.
Ijọba orilẹede naa ni 485,000 iwe aṣẹ lati kẹkọọ loun yoo fi sita.
Ijọba ni adinku yoo tun ba eleyii sii lọdun 2025 ati 2026 pẹlu ida 10% tori 437,000 iwe aṣẹ lati kẹkọọ loun yoo fi sita lọdun 2025.
Ninu atẹjade kan eyi ti o ṣẹṣẹ fi sita ni ijọba Canada ti fidi ọrọ yii mulẹ.
Ijọba ṣalaye siwaju si ninu atẹjade ọhun pe iye iwe aṣẹ lati ṣiṣẹ ati lati kawe kan naa loun maa fi sita fun ọdun 2025 ati 2026.
Ijọba mu adinku ba iwe aṣẹ lati kẹkọọ ati ṣiṣẹ fawọn oṣiṣẹ ati akẹkọọ ti wọn fẹ kẹkọọ gboye keji ni fasiti at'awọn to fẹ kẹkọọ gboye Ọmọwe.
Ijọba tun ṣe atunṣe lori anfani tawọn akẹkọọ ti wọn ti kẹkọọ jade yoo ni lati ṣiṣẹ lẹyin ti wọn ba ti kẹkọọ tan.
Ijọba ṣe adinku iwe aṣẹ lati ṣiṣẹ fawọn iyawo ati ọkọ awọn akẹkọọ to n kẹkọọ gboye keji ni fasiti si awọn to maa lo ọdun kan ati oṣu mẹrin nikan lati pari eto ẹkọ wọn.
Ijọba tun ṣe adinku iwe aṣẹ lati ṣiṣẹ lọdun 2024 yii fawọn iyawo ati ọkọ awọn oṣiṣẹ ilẹ okeere lorilẹede Canada.
Ẹwẹ, Olootu ijọba orilẹede Canada, Justin Trudeau, ti sọ pe oun yoo tun mu adinku ba iye wakati tawọn oṣiṣẹ lati ilu okeere fi n ṣiṣẹ ni Canada.
Trudeau ni "a o mu adinku ba owo oṣu to kere, a o si tun mu adinku ba iye wakati tawọn oṣiṣẹ lati ilu okeere fi n ṣiṣẹ."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Wo awọn amuyẹ ti o nilo fun iwe aṣẹ lati ṣiṣẹ ati kẹkọọ ni Canada

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ọdọọdun l'awọn akẹkọọ ọmọ Naijiria at'awọn to n wa iṣẹ maa n rinrin ajo lọ si Canada.
Lai deena pẹnu, igbesẹ tuntun ti ijọba Canada kede yii yoo ṣakoba fawọn akẹkọọ ati awọn oṣiṣẹ ilẹ okeere ni Canada tori ijọba ti sọ pe oun yoo faye gba awọn iyawo ati ọkọ lati ṣiṣẹ l'awọn ẹka toun ba ti nilo wọn nikan.
Awọn eeyan ilẹ okeere to maa n lanfaani lati jẹ olugbe Canada fun igba diẹ naa yoo dinku lati ida 6.5% si 5% laarin ọdun 2025 si 2027.
Eleyii yoo wa ninu atẹjade ti ijọba yoo fi sita lọjọ kinni oṣu Kọkànlá ọdun 2024 yii.
Awọn akẹkọọ to fẹ gboye keji ni fasiti at'awọn to n kẹkọọ lati gboye Ọmọwe yoo nilo lati gba iwe ijẹri lati ẹkun wọn.
Awọn akẹkọọ ni fasiti Canada to ba fẹ ṣiṣẹ gbọdọ yege ninu idanwo ede Canada meje CLB, eyi jẹ ọkan lara amuyẹ lati ṣiṣẹ ni Canada lẹyin ikẹkọọ-jade ti eto naa yoo si gberasọ lẹyin ọjọ kinni oṣu Kọkanla.
Awọn akẹkọọ gboye lati awọn ile ẹkọ giga kọlẹẹji ni Canada yoo si maa lanfaani lati ṣiṣẹ fun bi ọdun mẹta ti wọn ba kẹkọọ nipa iṣẹ t'awọn eeyan to mọ nipa rẹ ko pọ ni.
Ijọba Canada yoo si tun mu adinku ba iwe aṣẹ lati ṣiṣẹ fawọn iyawo ati ọkọ awọn akẹkọọ to fẹ gboye keji ni fasiti ti ko ni lo ju ọdun kan ati oṣu mẹrin lọ.
Bakan naa ni ijọba yoo tun mu adinku ba awọn eeyan ilẹ okeere to n wa iṣẹ ati to fẹ lọ kẹkọọ ni Canada.















