Bàbá Sàlá ló já ọ̀rá ẹ̀bùn eré ìtàgé lára mi lọ́dún 1990 – Gabriel Afolayan

Oríṣun àwòrán, Grabriel Afolayan
Gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Grabriel Olasubomoi Afolayan, ti ọpọ mọ si Grabriel Afolayan ti sọ pe lati kekere ni oun ti bẹrẹ iṣẹ tiata, ati pe ile ni oun ba iṣẹ ọhun.
Afolayan lo fi ọrọ naa lede ninu ifọrọwerọ kan to wa lori ayelujara.
O ṣalaye pe oloogbe Moses Olaiya, ti gbogbo aye mọ si Baba Sala, lo kọkọ fun oun lanfani lati kopa ninu ere bo tilẹ jẹ pe baba oun gan jẹ ogbontarigi oṣere.
"Asiko ti mo ba Tade Ogidan ṣe ere lo mu ki irawọ mi tan"
O ni “ti mo ba ranti daadaa, ọdun 1990 ni mo kọkọ kopa ninu ere ori itage bo tilẹ jẹ pe kii ṣe ninu ere ti baba mi, ere ọrẹ wọn ni mo kopa ninu rẹ.
“Inu ere tiwọn ni mo ti kọkọ kopa, awọn ni wọn ja ọra lara ẹbun to sọ mi di ohun ti mo da lonii yii.”
Nigba ti yoo di ọdun 2003, Afolayan ṣalabapade ọgbẹni Tade Odigan, to jẹ agba ọjẹ ninu iṣe oludari ere.
Gẹgẹ ohun to sọ, asiko to ba Tade Ogidan ṣiṣẹ ni irawọ rẹ ṣẹṣẹ bẹrẹ si n tan gẹgẹ bii oṣere lẹyin to kopa ninu ere ‘Madam Dearest.’
“Yatọ si ere ori itage, mo tun maa n kọ orin”
Afolayan sọ pe iṣẹ ere ori itage jẹ iṣẹ to rọrun fun oun atawọn mọlẹbi oun marun un mi to n ṣe iṣẹ naa.
Amọ o ṣalaye pe ohun ti awọn yan laayo ni iṣẹ naa, eredi ree ti awọn ko fi ri bii iṣẹ lile, ti ko si pa awọn lara.
Ṣugbọn pẹlu gbogbo ẹbun yii na, Afolayan tun n kọ orin yatọ si iṣẹ tiata to yan laayo.
O ṣalaye pe “a ti ṣe orin rẹpẹtẹ o, a ti sẹ awo orin bii meji, a dẹ tun ti ṣe eyii ti awọn oloyinbo maa n pe ni ‘EP’ ti orin ibẹ kii pọ.
“Ọdun 2011 ni mo gbe orin ‘Kokoro Ife’ jade, ti gbogbo aye fẹran, lẹyin iyẹn, a ṣe Awelewa…”
O ṣalaye pe oun ti gbe oniruru orin jade, oun yoo si tun gbe awo orin mii jade laipẹ.
Afolaya pari ọrẹ rẹ pe oun ko ni di eyikeyi ninu ọmọ oun to ba fẹ ṣe iṣẹ ere ori itage lọwọ, niwọn igba ti ọmọ naa ba nifẹ si iṣẹ ọhun tọkantọkan, to si ni ẹbun rẹ.















