Ta ni Okpebholo Monday gómìnà tuntun tó bọ́ sípò ní ìpínlẹ̀ Edo?

Oríṣun àwòrán, X/Edo ccommunity
Okpebholo Monday ni ajọ eleto idibo INEC kede pe o wọle ibo gomina ipinlẹ Edo lẹyin ti ajọ naa ka gbogbo esi ibo to waye ni ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa nipinlẹ naa tan.
Ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni Okpebholo Monday to ṣẹṣẹ wọle ibo gomina nipinlẹ Edo.
Ọgbẹni Monday la oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Asue Ighodalo mọlẹ pẹlu 291,667 si 247,274 lati wọle ibo naa.
Olumide Akpata, oludije fẹgbẹ oṣelu LP ti ibo to ri jina sawọn oludije APC ati PDP lo ṣe ipo kẹta ninu eto idibo naa to waye lọjọ Abamẹta tii ṣe ọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹsan an ọdun 2024 yii.
Ta ni Okpebholo Monday to wọle ibo gomina ipinlẹ Edo?

Oríṣun àwòrán, x/edo community
Ọdun 1970 ni a bi Okpebholo si ilu Uromi nipinlẹ Edo.
Iwadii fihan wi pe oniṣowo ni Okpebholo Monday ti ajọ INEC kede wi pe o wọle ibo gomina ipinlẹ Edo i ṣe.
Bakan naa, Ọgbẹni Monday tun ni sẹnẹtọ to n ṣoju ẹkun idibo Edo Central lọwọ lọwọ nile aṣofin agba niluu Abuja.
Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ, ko la ko ṣagbe lawọn obi Okpebholo jẹ ti wọn si wo o dagba pẹlu ẹkọ ile to ye kooro.
Ilu Uromi naa ni Okpebholo ti lọ si ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati ile ẹkọ girama.
Okpebholo tẹsiwaju ẹkọ rẹ nile ẹkọ giga fasiti UNIBEN nibi to ti kẹkọọ gboye ninu ẹkọ imọ nipa ọrọ aje ati iṣẹ ọgbin.
Okpebholo tun tẹsiwaju lẹnu ẹkọ rẹ lẹyin to gba oye keji ni fasiti ninu ẹkọ nipa didari awujọ ni fasiti UNIBEN kan naa.
Ko tan sibẹ o, Okpebholo tun tẹsiwaju lẹnu ẹkọ rẹ ni fasiti UI niluu Ibadan nibi to ti kẹkọọ gboye Ọmọwe ninu ẹkọ nipa eto ọrọ aje ati iṣẹ ọgbin.
Awọn ileri ti Okpebholo Monday ṣe ko to wọle ibo gomina Edo
Eto ilera to gbooro fun awọn obinrin, ọmọde ati awọn oṣiṣẹ fẹhinti, nipasẹ eto ilera adojutofo.
Idagbasoke eto ẹkọ nipasẹ owo ọfẹ, atungbeyẹwo owo ile ẹkọ, ati ẹkọ ọfẹ fun awọn akẹkọọ ipinlẹ Edo.
Ipese ọrọ ati iṣẹ yanturu, eyi ti yoo sọ awọn araalu di ẹni to n da iṣẹ silẹ dipo ẹni to n wa iṣẹ.
Riro eto aabo lagbara nipa ṣiṣe amulo owo eto aabo to jẹ ti Edo, lati daabo bo awọn agbẹ, oniṣwo, awọn oludokowo ati araalu.















