Ìyàwó gómìnà ìpínlẹ̀ Akwa Ibom Patience Eno jáde láyé

Aworan Patience Eno to doloogbe

Oríṣun àwòrán, Akwa Ibom State govt/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo ti sọ pe iyawo gomina ipinlẹ Akwa Ibom ti jade laye.

Kọmiṣọna fun eto iroyin ni ipinlẹ naa, Ini Ememobong lo kede iku Arabinrin Patience ninu atẹjade kan to fi sita laarọ oni ọjọ Ẹti.

Gẹgẹ bi Ọgbẹni Ememobong ṣe sọ ninu atẹjade naa, aya gomina Akwa Ibom ku nile iwosan kan l’Ọjọru ọjọ kẹrindinlogbọn oṣu Kẹsan an nibi tawọn ẹbi rẹ ti wa pẹlu rẹ.