Ladoja kó ipa ribiribi lórí àwọn ìgbésẹ̀ mi nínú ètò òṣèlú - Makinde

Aworan Rashidi Ladoja ati Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ti ṣe fi afihan ipa ti Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba(Sẹnetọ) Rashidi Ladọja ko lori bi o ṣe ti ẹsẹ bọ inu eto oṣelu.

Makinde to sọrọ ni ibi ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọrin ọdun ti wọn ṣe fun Ọba Ladọja l'Ọjọru fi kun ọrọ rẹ wi pe ko si ija kankan laarin oun ati Gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹri naa, lodi si gbọyisọyi to n lọ n'igboro.

O tẹsiwaju wi pe oun o tẹsiwaju lati kẹkọọ lara ọgbọn, iriri ati ipo adari Ladọja. O ni botilẹ jẹ wi pe Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan ti ṣe awọn nnkan rere ti o pọ fun ipinlẹ Ọyọ saaju asiko yii, sibẹ, iṣẹ rere rẹ ṣi n tẹsiwaju fun idagbasoke ipinlẹ naa.

Makinde ba Ladọja yọ lorukọ ile Ibadan ati ipinlẹ Ọyọ l'apapọ, pẹlu alaye wi pe ajọṣepo to danmọran wa laarin awọn mejeeji.

Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Ọyọ tun fi anfani ipejọpọ naa tan imọlẹ si ohun ti awọn eeyan kan n sọ wi pe gbogbo ilẹ to wa ninu ilu lo ti fi kọ awọn ileigbe alakọpọ, "Housing Estates".

Makinde ni awọn idagbasoke kan gbọdọ waye, lai ro ti inira ti wọn mu lọwọ lasiko yii.

O fi kun ọrọ rẹ wi pe gbogbo ibi ti ipenija ba ti n waye ninu eto idagbasoke ilu ni ijọba oun yoo dasi.

Makinde jiyan ẹsun ti wọn fi kan an wi pe o n ja ilẹ awọn eeyan gba lọna aitọ, gẹgẹ bi o ṣe ṣalaye wi pe gbogbo ipa ni iṣakoso oun n sa fun anfani ipinlẹ Ọyọ ati awọn eeyan inu rẹ.