Kílódé tí Nàìjíríà ṣe n fẹ́ kí United Nations mójú kúrò lára gbèsè tó jẹ?

Shettima

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Igbakeji Aarẹ Naijiria, Kashim Shettima to n ṣoju Aarẹ Bola Tinubu nibi apero Agbaye ti United Nations Assembly to n lọ lọwọ ti bẹbẹ pé ki wọn yọnda awọn gbese ti Naijiria ati awọn orilẹ-ede mii to n dagba jẹ fún wọn.

Shettima sọ pe ọpọ awọn orilẹ-ede to n dagba yii lo n koju iṣoro to pọ ni eyi ti wahala gbese tun n kun niwaju wọn.

O tun fi kun un pe oun n fe ifọwọsowọpọ ajọ Agbaye lati rii pe Naijiria ri awọn owo ti awọn alajẹbanu kan ji gbe ló sile okeere gba.

Bakan naa lo tun sọ pe ki wọn fun Naijiria ati ile Adulawọ ni ipo kan ninu awọn ti wọn jẹ aṣoju ile ninu igbimọ eto aabo ninu ajọ agbaye.

Kini Idi ti Naijira ṣe fẹ ki wọn yọnda gbese naa ni pato?

Olukọni nipa eto iṣuna ati ọrọ aje nile ẹkọ giga imọ ẹro ni ipinlẹ Kano, Malam Lawal Habib Yahaya salaye fun BBC pe ida aadọrin ninu ọgọrun un owo to n wọle fun Naijiria ni wọn fi n san gbese ti awọn Adari kan ti na ni inakuna.

O ni nitootọ ko si orilẹ-ede ti ko jẹ gbese lasiko yii sugbọn ti Naijiria ti kọja agbara bayii. O ni eyi si jẹ ankoo fawẹli fun ọpọ orilẹ-ede ilẹ Afirika bayii ki a to wa sọ ti iwa ajẹbanu to kari.

Mallam Yahaya sọ pe iye ti Naijiria n san gẹgẹ bi ele ori gbese gan an ko le jẹ ki wọn ri owo ṣe nkan mii to yẹ ni ilu.

O ni pe yiyọ iranlọwọ ori epo, ori ina mọnamọna ati eto ẹkọ Fasiti ni Naijiria ko jẹ ki nkan rọrun fun ara ilu lasiko yii.

Eelo ni Gbese Naijiria?

Akọsilẹ ileeṣẹ Nigeria Bureau of Statistics (NBS) eyi ti Nigeria Debt Management Agency fi sita fihàn pe gbese Naijiria ni osu keta ọdun yii ti di N121.67 tiriliọnu naira to dabi 91.46 owo dọla ilẹ Amerika.

Ijọba apapọ funra rẹ ti ya owo to to 46.290.28 tiriliọnu naira lati ilẹ okeere eyi to jẹ owo to ju owo iṣuna ọdun meji Naijiria lọ. Eyi si n waye lasiko ti iroyin kan jade pe Banki Agbaye tun fẹ ya Naijiria ni owo dọla to le ni biliọnu kan laipẹ.