Èèyàn mẹ́ta dèrò àhámọ́ lórílẹ́èdè Benin lórí ẹ̀sùn pé wọ́n fẹ́ dìtẹ̀ gbàjọba

Aworan aarẹ Patrice Talon orilẹede Benin

Oríṣun àwòrán, AFP

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Eeyan mẹta ni a gbọ pe wọn dero atimọle lorilẹede Benin lori ẹsun wi pe wọn fẹ ditẹ gbajọba orilẹede naa.

Gẹgẹ bi iroyin tawọn alaṣẹ orilẹede naa fi sita ṣe sọ, minisita ere idaraya tẹlẹri, Oswald Homeky, oniṣowo ati ọrẹ Aarẹ Patrice Talon Benin, Olivier Boko ati olori awọn ọmogun kan lorilẹede Benin lawọn eeyan mẹta naa ti wọn sọ pe wọn n gbero lati ditẹ gba ijọba lọjọ Ẹti ọsẹ yii.

Olupẹjọ sọ pe ijọba fọwọ ofin mu minisita tẹlẹri nigba to n gbe baagi owo mẹfa fun olori ọmogun ti wọn jọ n gbero lati ditẹ gba ijọba.