Ìjọba ṣe àlékún owó àjẹmọ́nú àwọn àgùnbánirọ̀ láti N33,000 sí N77,000 lóṣù

Aworan awọn agunbanirọ

Oríṣun àwòrán, NYSC/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ijọba apapọ ti buwọlu alekun owo ajẹmọmu awọn agunbanirọ to n ṣe iruulu lati N33,000 to wa tẹlẹ si N77,000.

Agbẹnusọ ajọ NYSC to n ṣakoso awọn akẹkọọgboye lati ile ẹkọ giga fasiti ati ti gbogbonṣe, Caroline Embu, lo fọrọ yii lede ninu atẹjade kan to sita nirọlẹ Ọjọru.

Arabinrin Embu ni alekun owo ajẹmọnu awọn agunbanirọ wa ni ibamu pẹlu alakalẹ ajọ to n ri si ọrọ owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ ni Naijiria.

O ni lati oṣu Keje ọdun 2024 yii ni ijọba yoo ti bẹrẹ sii maa sanwo naa fawọn agunbanirọ.

Ṣaaju ni ọga agba ajọ NYSC, Ọgagun YD Ahmed, ti pe sun alekun owo ajẹmọnu awọn agunbanirọ nigba to ṣabẹwo si alaga igbimọ to n ri si ọrọ owo oṣu awọn oṣiṣẹ ni Naijiria, Ekpo Nta.

Agbẹnusọ ajọ NYSC sọ pe ọga agba ajọ naa ti gboṣuba rabandẹ fun ijọba apapọ lori alekun owo ajẹmọnu awọn agunbanirọ to ṣe.

Ọgagun Ahmed ni igbesẹ ijọba yii yoo fawọn agunbanirọ ni iwuri lati ṣiṣẹ takun takun nibi ti onikaluku wọn ti n sin ilẹ baba wọn.

Ni ọdun 2020 ni ijọba ṣe alekun owo ajẹmọnu awọn agunbanirọ lati N19,800 si N33,000 lẹyin ti ijọba apapọ buwọlu N30,000 gẹgẹ owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.

Ẹwẹ, ninu oṣu Keje to lọ ni Aarẹ Bola Tinubu buwọlu N70,000 gẹgẹ bi owo oṣu tuntun oṣiṣẹ to kere julọ ni Naijiria lẹyin oniruuru ijoro laarin apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ ati ijọba.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post