Kí ló dé tí CBN fi se àfikún èlé orí owóyàá sí 27.25%, bí NBS ṣe ní bíi 5m ọmọ Nàíjíríà ní kò níṣẹ́ lọ́wọ́?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ oluṣiro NBS ti kede wi pe iye awọn ti ko ri iṣẹ ṣe lorilẹede Naijiria tun ti lọ soke si bayii pẹlu ida 1.2%.
Ajọ NBS ṣalaye pe eleyii ṣẹlẹ lẹyin ti banki apapọ Naijiria ṣe afikun ele ori owooya lọ si ida 27.25%.
Ajọ naa ṣalaye wi pe ida 5.3% awọn to ti too ṣiṣẹ ṣugbọn ti wọn ko ri iṣẹ ṣe ni iye awọn ti ko ri iṣẹ ṣe da ni oṣu mẹta akọkọ ninu ọdun 2024 yii.
Gẹgẹ bi atẹjade ti ajọ NBS fi sita ṣe sọ, ida 4.3% lawọn ọkunrin ọmọ Naijiria ti wọn ko ri iṣẹ ṣe nigba tawọn obinrin di ida 6.2%.
Bakan naa ni NBS sọ siwaju sii pe ida 6.0% awọn eeyan ti ko ri iṣẹ ṣe yii ni wọn n gbe igboro nigba ti ida 4.3% n gbe ni igberiko.
Ida 8.4% awọn ọdọ ni ko ri iṣẹ ṣe bayii gẹgẹ bi atẹjade ọhun ṣe sọ.
‘’Airiṣiṣẹ ṣe laarin awọn eeyan ti wọn ti kẹkọọ gboye ju oye akọkọ fasiti lo ti di ida 2.0% bayii, nigba ti ida 9.0% jẹ iye awọn eeyan to kawe ju iwe girama lọ.
Ida 6.9% lawọn ti ko ri iṣẹ ṣe laarin awọn ti ko ka ju iwe mẹwaa lọ, nigba ti ida 4.0% jẹ awọn ti ko ri iṣẹ ṣe laarin awọn ti ko kawe ju iwe alakọbẹrẹ lọ loṣu mẹta akọkọ ninu ọdun 2024 yii.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Banki apapọ Naijiria CBN ṣe afikun ele ori owooya
Ọpọ awọn olokowo lo ti n pariwo wi pe bi banki apapọ Naijiria ti ṣe afikun ele ori owooya lati ida 27.25% lọ si 26.75% yoo ṣe ipalara fun idokowo ati idagbasoke ọrọ aje orilẹede Naijiria.
Awọn olokowo yii sọ pe igbesẹ banki CBN yii yoo jẹ ko nira gan an fawọn olokowo to ba fẹ yawo ṣe owo ni Naijiria.
Wọn ni ọpọ awọn olokowo ni yoo maa jẹ ile ifowopamọ ni gbese to pọ pẹlu afikun ele ori owooya ti CBN ṣe yii.
Nigba ti o n sọrọ lori iye awọn ọmọ Naijiria ti ko ri iṣẹ ṣe ti ajọ NBS gbe nọmba rẹ sita, onwoye nipa ọrọ aje, Ejike Nwuba, sọ fun iwe iroyin Vanguard wi pe awọn ti ko ri iṣẹ ṣe ni Naijiria pọ ju ida 5.3% ti ajọ NBS kede lọ.
Adari ajọ CPPE to n ri si ipolongo okowo aladani, Ọmọwe Muda Yusuf, naa sọ pe igbesẹ CBN lati ṣe afikun ele ori owooya yoo ṣakoba nla fun ọrọ aje.
Ọmọwe Yusuf sọ pe o buru jai wi pe asiko tawọn olokowo atawọn oniṣowo aladani n pariwo lori ọwọngogo nkan elo ti wọn n ra ni banki CBN tun lọ ṣe afikun ele ori owooya.
O ni igbesẹ banki CBN pẹlu ele ori owooya yii ko ṣenu ire fawọn olokowo ati erongba wọn lati ri pe ọrọ aje Naijiria dagba soke sii.
Ọmọwe Yusuf ni ohun tawọn olokowo fẹ lasiko yii ni pe ki wọn ri imu mi, kii ṣe eto tabi igbesẹ ijọba ti yoo tun fun wọn lọrun sii.















