Àwọn ọmọ Kenya n ṣiṣẹ́ àṣelàágùn lóko òdòdó fáwọn òyìnbó

Ododo ni Kenya

Oríṣun àwòrán, Kate Stanworth

    • Author, Ismail Einashe
    • Role, Naivasha
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ni agbegbe Naivasha lorilẹede Kenya , Anne jokoo sile oni yara meji kan lẹyin saa awọn ododo tan.

Anne(Ki se ọrukọ rẹ gangan) jẹ obinrin ti ko si ni ile ẹkọ, to si jẹ ọkan lara awọn obinrin lorilẹede Kenya to n sisẹ ni agbaala ododo ni agbegbe Naivasha ni apa ariwa olu ilu Kenya, Nairobi.

Oko ododo yii lo jẹ ti awọn oyibo.

Ọdun kẹdogun ree ti Anne ti n sisẹ ni agbaala ododo lorilẹede Kenya, to jẹ ileeṣẹ to n gba eeyan ju lọ.

Iwadii fihan pe ileeṣẹ to n gbin ododo yii n gba oṣiṣẹ ẹgbẹrun lọna aadọjọ, to si n pa owo toto bilọnu kan naira si apo ijọba lọdun.

Pẹlu bi o ṣe n sisẹ to, owo oṣu rẹ to le ni ẹgbẹrun dọla ko mu ayipada ba igbesi aye rẹ lẹyin ọpọ ọdun lẹnu iṣẹ.

Ododo ni Kenya

Oríṣun àwòrán, Kate Stanworth

"Iṣẹ tawọn osisẹ n se lojumọ nira pupọ ṣugbọn wọn ko ni ọna miiran ju lati ṣe iṣẹ naa"

Owo naa ni ko to lati na nitori ọwọngogo to gbode lorilẹede Kenya.

Ni ipari oṣu, owo ti Anne n gba ni ko lati jẹun, ti ko si ni jẹun nigba miiran.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

“O ni lati wọ oko igbese ko to le jẹun,” o ṣalaye bi o ṣe ni lati yawo ran ọmọ rẹ ọkunrin, ẹni ọdun nmẹtalelogun lọ si ile ẹkọ fasiti ni Nairobi.

Ni owurọ kutu, Anne ati awọn ẹgbẹlẹgbẹ oṣiṣẹ yooku ni lati tẹle ọkọ ileeṣẹ wa si ileeṣẹ , ti yoo gbe wọn lọ si oko, ti wọn yoo si ma gun apata ninu oorun.

Iṣẹ bẹrẹ ni ago meje abọ, to si ma lọ ni ọjọ mẹfa laarin ọsẹ. Ni ọjọ Aiku, yoo lọ si ile ijọsin.

Wakati mẹjọ ni o fi ma ṣisẹ ni oko ododo, o ṣalaye pe nigba miiran wọn ma fi wakati mẹta kun wakati iṣẹ rẹ, ti wọn ko si ni fi owo kun owo rẹ.

Anne ni iṣẹ ti wọn gbe awọn oṣiṣẹ lati se lojumọ ni lo nira pupọ ṣaugbọn wọn ko ni ọna miiran ju lati ṣe iṣẹ naa.

O ni ti oun ba kọ lati sisẹ naa, o ni lati kọ iwe si ọga rẹ, ti yoo si ṣalaye idi ti o fi kuna lati se iṣẹ.

“Ti a ko ba se iṣẹ naa, wọn le le oṣiṣe jade.”

Ni ọdun 2023, Anne se airẹ, to si ni iṣoro ẹjẹ, eyi ti wọn ko ba iwosan si, le fa iku ojiji.

O bẹrẹ si ni ma rẹ, ti ko si le mi daada, eyi to jẹ ki iṣẹ le pupọ fun un.

O lọ ri nọọsi ninu ọgba oko naa to fun ni oogun, to si gba laaye pe ko si mi fun wakati diẹ ko to ni ko pada si ẹnu iṣẹ.

“Mo sọ fun pe o rẹ mi lati siṣẹ”, Anne se iranti

Anne ni o nira pupọ lati jẹ nọọsi naa ri pe o rẹ oun gan sugbọn o pada gba, to si dari rẹ si ọdọ nọọsi mii nita oko.

Pẹlu bi o ṣe rẹ to, to si tun gba iwosan, ọjọ kan pere ni wọn fun lati si mi

“O dun mi nitori airẹ si n se mi.” O sọ

Nigba ti ọrọ yoo wa bajẹ, o ni kọ lẹta si ọga rẹ, to si ṣalaye idi ti ko le fi ṣe awọn iṣẹ to yẹ ko se lọjọ naa.

Margaret, oṣiṣẹ mii ninu oko ododo naa ni wọn ma fn fi tipatipa fun awọn oṣiṣẹ lati fọn kẹmika si awọn ododo lai fun wọn ohun ibomu.

Aworan obinrin pelu ododo

Oríṣun àwòrán, Kate Stanworth

"Ọpọ obinrin lo n koju ifipabanilopọ lati ọdọ awọn oṣiṣẹ to jẹ ọkunrin"

Margaret, (Ki se orukọ rẹ gangan) ni a lati wa ba ni ile akẹgbẹ rẹ ni alẹ agbegbe kan ni Naivasha.

Ẹru n ba lati sọrọ sita lori ohun to ṣẹlẹ.

“Ẹnikẹni ko bikita,” o sọ.

Margaget ni ọpọ igba ni oun fọnu sita fun awọn ọga nipa ohun ti wọn la kọja.

“Wọn n pariwo mọ ọkunrin, pariwo mọ obinrin,” o ṣalaye. “Wọn ma pariwo mọ gbogbo wa.

Wọn ko bikita, wọn jẹ ọmọ Kenya.”

O ni ọpọ obinrin lo n koju ifipabanilopọ lati ọdọ awọn oṣiṣẹ to jẹ ọkunrin.

Ida Ogoji ni ida iye ododo to n lọ si ilẹ Europe lati orilẹede Kenya, ti wọn si n ta ni ọja kaakiri.

Gẹgẹ bii abiyamọ pẹlu ọmọ kan, eyi to nilo iranlọwọ, Anne ni oun ko ni ọna miiran ju pe ko tẹsiwaju ninu iṣẹ rẹ ni oko ododo. Ọpọ anfani mii lo ti ri ni Naivasha suggbọn ko fẹ ki owo ma wa lọwọ rẹ rara.

“Ti Ọlọrun ba ran mi lọwọ, ma tẹsiwaju,” Anne ṣalaye