Àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ ní àwọn òṣèré tíátà ń tàbùkù ìṣẹ̀ṣe nínú fíìmù, àwọn òṣèré fèsì
Ọmọwe Fayemi Fatunde Fakayode, Aarẹ Agbe’faga ilẹ Yoruba to tun jẹ Jagunmolu Awo Agbaye ti sọ pe ọpọlọpọ nnkan lawọn to n ṣere tiata ati ere idẹrinpoṣonu ti wọn n pe ni sikiiti n ṣe to n ṣakoba fun iṣẹṣe, aṣa ati iṣẹ ọmọ Oduduwa.
Jagunmolu Awo Agbaye fidi ọrọ yii mulẹ nibi ijiroro to waye laarin awọn oṣere tiata Yoruba atawọn oniṣẹṣe niluu Ibadan.
Aarẹ Agbef’aga ni wọn maa n ṣafihan iṣẹṣe lọna tawọn eeyan yoo fi korira iṣẹṣe.
O ni ‘’wọn maa n jẹ kawọn eeyan ri awọn oniṣẹṣe bi eeyan buburu.
Wọn le ṣe afihan babalawo gẹgẹ bi ẹni to n pa eeyan, tabi ẹni to n ṣe ogun ika to jẹ wi pe wọn a wa ṣafihan awọn ẹlẹsin mii gẹgẹ ẹni to n tu eeyan silẹ.
Bakan naa ni wọn tun maa n ṣafihan iṣẹṣe gẹgẹ ohun ti ko ni agbara kankan.''
''Wọn maa n ṣe afihan babalawo gẹgẹ bi ẹni ti yoo maa bawọn eeyan ṣogun owo tabi ti yoo maa pa eeyan''
Ọmọwe Fakayode fikun ọrọ rẹ pe ''nigba mii, awọn oṣere tun maa n fi aṣa wa wọlẹ, wọn le mu ẹku egungun ki wọn gbe wọ obinrin lọrun eleyii to jẹ eewọ ninu aṣa ati iṣe Yoruba.
A tun ri pe ti wọn ba fẹ lo babalawo, wọn kii lo awọn to jẹ babalawo gidi, awọn ti ko mọ nkan kan nipa iṣẹṣe ni wọn maa n lo.
Nkan ti ko bara mu ni iru awọn eeyan bayii saba maa n sọ.
Wọn le ṣe afihan babalawo ko wọ aṣọ radarada, nigba ti pasitọ tabi alfa yoo wọ aṣọ to dara.
Wọn tun le ya ori eeyan sara ogiri abawọle babalawo ti a si mọ pe ọrọ ko ri bẹẹ.
Bakan naa ni wọn maa n ṣe afihan babalawo gẹgẹ bi ẹni ti yoo maa bawọn eeyan ṣogun owo ti yoo maa pa eeyan.
Aworan ti wọn fi n han awọn eeyan nipa iṣẹṣe ko tiẹ jọ bi iṣẹṣe ṣe ri rara.’’
Nigba mii gbogbo ohun ti a n ṣe, a kan n ṣe ni tiwa ni fun igbadun tiyin - Jaiye Kuti
Nigba to n fesi, gbajumọ oṣere Jaiye Kuti sọ pe oriṣiiriṣii ẹsun lawọn oniṣẹṣe fi maa n kan awọn oṣere tiata.
Arabinrin Kuti sọ pe awọn kan lo kọkọ maa n ro nipa ere ti wọn fẹ ṣe ki wọn to pe awọn oṣere wi pe ki wọn kopa ninu rẹ.
O ni kii ṣe wi pe awọn oṣere n ba iṣẹṣe jẹ.
Kuti sọ pe ‘’nigba mii gbogbo ohun ti a n ṣe, a kan n ṣe ni tiwa ni fun igbadun tiyin.
Bi oyinbo ṣe n ṣe tiẹ bi gbogbo wọn ṣe n ṣe ti wọn, tori naa kii ṣe ẹbi wa.
Ti a ba ṣafihan ile babalawo sabẹ igi ọgẹdẹ, o ni ohun ti a fẹ tọka si.
A ti ṣe babalawo to n ṣe daadaa, a si tun ti ṣe babalawo to n ṣe buruku.’’
Oṣere miran Taiwo Ibikunle sọ pe ‘’ọpọlọpọ igba ni a maa n ṣere ti awọn ẹlẹsin Kristẹni maa n wa nibẹ ti a maa pe wọn ni ẹlẹsin eke.
Bẹẹ naa ni a ri ninu awọn ẹlẹsin musulumi, bo dẹ ṣe ri naa niyii laarin awọn oniṣẹṣe.
Ti a ba wo o daadaa awọn oniṣẹṣe yii kan naa lawọn eeyan n lọ sọdọ wọn fun ogun owo, awọn naa lawọn pasitọ atawọn alfa maa n lọ ba lati gba afọṣẹ lọwọ wọn.
Nitori naa, laarin wa gẹgẹ bii Yoruba, a kọkọ nilo lati ba ara wa sọrọ ki a dẹ ṣe ẹsin wa bo ti tọ ati bo ti yẹ.
Aarẹ Agbe’faga Agbaye ṣalaye siwaju si pe ki ọrọ naa to di ohun tawọn yoo pada gbe de ile ẹjọ lo jẹ kawọn pe ipade pẹlu awọn oṣere tiata lati sọ ẹdun ọkan awọn.
















