Bí mo bá wọlé gẹ́gẹ́ bíi gómìnà Ondo, mo máa kọ́ ojú òpó ọkọ̀ ojú irin sí orí omi – Kunle Ajayi, olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú AAC
Ni ọjọ kẹrindinlogun oṣu kọkanla ọdun 2024 ni eto idibo si ipo gomina ni ipinlẹ Ondo yoo waye.
Saa ti oloogbe Rotimi Akeredolu bẹrẹ ṣugbọn ti iku ko jẹ ko le pari, ki igbakeji rẹ, Lucky Ayedatiwa to gbe e lati ibẹ yoo pari.
Lara awọn to n lepa ati bọ si ile ijọba ipinlẹ Ondo to wa lagbegbe Alagbaka ni Ọgbẹni Kunle Ajayi to n dije fun ẹgbẹ oṣelu AAC wa.
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, Kunle Ajayi ṣalaye pe bi wọn ba ko gbogbo awọn oludije pọ lati wo ati maa ṣe bọ wọn pẹlu iriri, o da oun loju pe iriri oun ninu oṣelu ju ti ọpọ awọn to n ba oun dije lọ.
- "Ọkùnrin mẹ́rin sí márùn-ún ni mo ń wọ́ ara fún lójúmọ́, àwọn míràn máà ń bèèrè ‘ìtura’ lẹ́yìn ara wíwọ́"
- Awọn akọrin Islam mẹ́ta, tó ṣúnmọ́ Rukaya Gawat, sọ̀rọ̀ lórí ohun tó fa ikú rẹ̀
- 'Bí oyún oṣù méje ni ikùn mi ṣe tobí nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìju tó ń bá mi fínra'
- Sheik L'Agbaji sọ̀rọ̀ lórí fídíò òun àti Wòólì Genesis tó fa awuyewuye lórí ayélujára
Mo mọ nipa oṣelu lati kekere nipasẹ baba baba mi to ba awolọwọ ṣiṣẹ -Kunle Ajayi
Lara awọn eto ti o ni oun yoo mojuto lasiko ti oun ba le wọle ni ọrọ eto ẹkọ.
Gẹgẹbi ọrọ rẹ, “eto ẹkọ tootọ” jẹ ohun kan to wa loke tente tabili awọn eto ti iṣejọba oun yoo kọkọ mojuto bi o ba le wọle.
O ni lati kekere loun ti kọ nipa oṣelu nipasẹ Baba Baba oun to fi igba kan ṣe kansilọ labẹ ẹgbẹ oṣelu Unity Party ti o si sun mọ Oloye Awolọwọ ati Ajaṣin pẹkipẹki.
Kunle Ajayi ṣalaye p eohun meji lo ta oun pọn si idi ọrọ oṣelu. Akọkọ ni bi awọn to dipo oṣelu mu ṣe mu aroye araalu lọkunkundun lawọn asiko kan sẹyin; titi kan bi awọn aṣiwaju ṣe maa n tete n kan si ohun to ba ku diẹ kaato lawujọ.
Ekeji si ni awọn ileeṣẹ ati lajọlajọ to jẹ oju ogo ijọba kọọkan nigba naa.





