Ìbẹ̀rùbojo la fi ń gbáyé - Àwọn ọmọ Áfíríkà ní Lebanon sọ̀rọ̀

Oríṣun àwòrán, Sharon Atyang
- Author, Priyanka Sippy
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Farai, akẹ́kọ̀ọ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ọmọ orílẹ̀ èdè Zimbabwe ni orí tábìlì kan nínú yàrá òun ní Beirut ni òun máa ń kó àwọn ìwé òun sí.
Àmọ́ lọ́sẹ̀ yìí, àwọn ìwé ìrìnnà rẹ̀ àti owó ló kó sí orí tábìlì náà báyìí.
“Mo ti ń gbáradì nítorí tí mo bá nílò láti sá kúrò ní ìlú yìí ní kíákíá,” Farai sọ.
Farai, ẹni tí a ṣe àyípadà orúkọ rẹ̀ nítorí ààbò, padà sí Lebanon ní oṣù Kẹsàn-án fún ìparí ètò ẹ̀kọ́ onípò kejì nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ “Mechanical Engineering” lẹ́yìn ìsinmi nílé.
O padà sí Lebanon pẹ̀lú èròńgbà pé láàsìgbò tó ń wáyé ní ẹkùn náà máa ti lọ sílẹ̀. Àmọ́ láti ìgbà tí Hamas ti ṣèkọlù sí Israel ní ọjọ́ Keje, oṣù Kẹwàá, ọdún 2023 ni Israel àti Hezbollah, tó jẹ́ ikọ̀ alákatakítí ẹ̀sìn tí Iran ń ṣe àtìlẹyìn fún àmọ́ tó fi ìkalẹ̀ sí Lebanon ti ń ju àdó olóró sí ẹnubodè ara wọn.
Ọ̀sẹ̀ yìí ni àwọn ni ó lágbára jùlọ fún Lebanon láti bíi ogún ọdún sẹ́yìn. Èèyàn tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà ni kò nílé lórí mọ́ láti ọjọ́ Ajé gẹ́gẹ́ bí àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ṣe sọ.
Iléeṣẹ́ ológun Israel ní àwọn ń ṣe àkọ̀tun ìkọlù sí gúúsù Lebanon àti agbègbè Beqaa pẹ̀lú èrò láti dojú ikọ̀ Hezbollah bolẹ̀ pátápátá.
Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá, èèyàn mọ́kàndínlógójì ló jáde láyé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ náà sì farapa nígbà tí àwọn ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ “pager” táwọn ọmọ ogun Hezbollah ń lò bẹ̀rẹ̀ sí ní bú gbàmù mọ́ wọn lọ́wọ́.
Hezbollah ní àwọn ń ṣe àtìlẹyìn fún àwọn èèyàn Palestine. Israel ní àwọn ń ran àwọn èèyàn àwọn tí wọ́n ti sá kúrò ní ilé wọn tó wà ní ẹnubodè lọ sí àríwá Israel.
Orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, UK, Australia, France, Canada àti India ti ṣèkìlọ̀ fáwọn ọmọ orílẹ̀ èdè wọn tó wà ní Lebanon láti kúrò níbẹ̀ kíákíá.
Àwọn ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ ní Lebanon sọ fún BBC News pé àwọn kò mọ nǹkan tó yẹ kí àwọn ṣe – bóyá kí àwọn dúró ní Lebanon ni tàbí kí àwọn padà sí orílẹ̀ èdè àwọn bíi Uganda, Cameroon àti Zimbabwe.
Ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì American University of Beirut (AUB), níbi tí Farai ti ń kẹ́kọ̀ọ́, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà àádọ́rùn-ún ló wà níbẹ̀ lábẹ́ ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ níbẹ̀.
Farai ní ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni ọkàn wọn kó sókè pàápàá, láti ìgbà tí àwọn ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ bú gbàmù mọ́ àwọn èèyàn lápò.
“A ò mọ ẹni tó gbé àdó olóro tó lè bú gbàmù lójijì sápò,” ó sọ.

Oríṣun àwòrán, AFP
Inú fu àyà fu lọ́gbà ilé ẹ̀kọ́
Ṣáájú àkókò yìí, ṣíṣe àbẹ̀wò sáwọn ọ̀rẹ́ àti lílọ fún ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ ló máa ń gbé Farai lọ sílé ẹ̀kọ́ àmọ́ tó jẹ́ pé tó bá fẹ́ lọ ra nǹkan ló máa ń gbe lọ sọ́gbà ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ báyìí.
Ọ̀pọ̀ àwọn ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni wọ́n ń ṣe lórí ayélujára báyìí. Ó ní tí òun bá lọ sí ọgbà ilé ẹ̀kọ́ àwọn, níṣe ni àwọn ń wà nínú ìbẹ̀rùbòjò.
“Ọkàn oníkálukú ló wà lókè, kódà bí a ṣe ń bá ara wa sọ̀rọ̀ lásìkò yìí ti yàtọ̀.
“Tí a bá parí ìkẹ́kọ̀ọ́, olùkọ́ wa yóò sọ pé kí a ri dájú pé à ń wà níbi tí ààbò wà tí àwọn náà yóò sọ bẹ́ẹ̀ padà fún nítorí a mọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní agbègbè wa.
“Kò sí ẹni tó lè sọ pé òun wà lábẹ́ ààbò tó dájú.”
Gbogbo ọ̀sẹ̀ yìí ni wọ́n fi máa ti ilé ẹ̀kọ́ AUB pa yàtọ̀ sí àwọn tó ń ṣiṣẹ́ tó ṣe kókó.
Ìkéde títi ilé ẹ̀kọ́ náà pa ló wáyé lẹ́yìn tí iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ẹ̀kọ́ ní kí gbogbo àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó jẹ́ ti ìjọba àti aládàni wà ní títì pa dòpin ọ̀sẹ̀.
Iléeṣẹ́ náà ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ ìjọba ni àwọn èèàn tí kò nílé lórí mọ́ látàrí ìkọlù Israel yóò máa lò fún ìgbà kan ná.

Oríṣun àwòrán, Sharon Atyang
Ṣíṣe ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ lórí ayélujára
Ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilẹ̀ Áfíríkà ní AUB ti pèsè àǹfàní fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà láti máa lọ sílé, lọ parí ẹ̀kọ́ wọn lórí ayélujára.
Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ló ní àǹfàní náà kò ní ṣeéṣe.
Sharon Atyang, akẹ́kọ̀ọ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n láti ẹkùn àríwá orílẹ̀ èdè Uganda ti wà ní ìpele tó kẹ́yìn fún ètò rẹ̀ nípa ìdàgbàsókè ìlú ní AUB.
Ó ní iná mọ̀nàmọ́ná àti ìpèsè ohun èlò ayélujára kò ní jẹ́ kó rọrùn fún òun láti parí ẹ̀kọ́ òun lórí ayélujára tí òun bá padà sílé.
Atyang ṣàlàyé pé ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ni òun ń jẹ àǹfàní rẹ̀, òun kò sì mọ̀ báyá wọ́n máa dá òun padà sí Lebanon tí gbogbo nǹkan bá paà sípò tí òun bá lọ sílé.
Adele (kìí ṣe orúkọ rẹ̀ gangan) láti Cameroon sọ pé kò ní rọrùn fún òun láti parí ètò ẹ̀kọ́ “radiology” tí òun ń ṣe lórí ayélujára.
Àmọ́ ó ní òun ti palẹ̀mọ́ àwọ báàgì òun nítorí tí ìkọlù míì bá tún wáyé ní Beirut.
Ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ “Mastercard Scholarship Program” máa ṣe ìrànwọ́ fún ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti ilẹ̀ Áfíríkà ní Lebanon.
Àjọ Mastercard Foundation ní àwọn ń àmójútó àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń lọ ní Lebanon àti pé àwọn ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú AUB láti pèsè ìrànwọ́ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́.
Agbẹnusọ wọn sọ pé AUB ń bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sọ̀rọ̀ lóòrè kóòrè, tí wọ́n sì ń pèsè àtìlẹyìn tó yẹ fún wọn.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíṣe ìrìnàjò ní Lebanon láti pápákọ̀ òfurufú ṣì wà ní ṣíṣí, ó ṣòrò láti lè rí ọkọ̀ òfurufú tí yóò gbé èèyàn. Ọ̀pọ̀ àwọn iléeṣẹ́ ìrìnnà òfurufú bíi Qatar Airways, Air France àti Lufthansa ni kò jẹ́ kí àwọn ọkọ̀ òfurufú wọn gbéra tàbí balẹ̀ sí Lebanon mọ́.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
'A ò lè mójútó ẹ̀kọ́ wa mọ́'
Akẹ́kọ̀ọ́ mìírà, Sharon, tó ń sọ̀rọ̀ láti yàrá rẹ̀ ní Beirut ní òun ń gbọ́ ohùn ọkọ̀ òfurufú àwọn ọmọ ogun Israel tí wọ́n ń fò káàkiri orílẹ̀ èdè náà.
“Mo wà ní yàrá ìkàwé mi ni mò ń gbọ́ ohùn, mo sáré àmọ́ kò sí ibi tí mo fẹ́ sá lọ, inú ilé ìgbọ̀nsẹ̀ mi ni mo sá sí.”
Ó ní ìbẹ̀rù pé ìkọlù mìíràn le wáyé nígbàkígbà ti mú kí ọkàn òun wà ní ìporuru tí kò sì jẹ́ kí àwọn le ṣe ohunkóhun.
Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ló ti bẹ olùkọ́ wọn láti fi ọjọ́ kún ọjọ́ tí wọ́n máa gbé iṣẹ́ àṣelátilé padà.
Ó ṣàlàyé pé àwọn ẹbí òun náà kò yé máa pe òun ní gbogbo ìgbà láti mọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí níbi tí òun wà.
Àwọn orílẹ̀ èdè Áfíríkà kọ̀ọ̀kan ti ń ko àwọn èèyàn wọn kúrò ní Lebanon.
Ìjọba Kenya ti bẹ̀rẹ̀ sí ní kó àwọn èèyàn wọn kúrò níbẹ̀.
Akọ̀wé àgbà àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè ní Kenya, Roseline Njogu ní àwọn ọmọ Kenya mẹ́sàn-án ló ti padà sílé nínú oṣù Kẹjọ.
Njogu rọ àwọn ọmọ Kenya míì tó bá fẹ́ kúrò ní Lebanon láti lọ forúkọ sílẹ̀ ní iléeṣẹ́ Kenya tó wà ní Lebanon. Àwọn ọmọ Kenya tó tó 26,000 ni ìgbàgbọ́ wà pé wọ́n ń gb é ní Lebanon.
Ní oṣù tó kọjá, agbẹnusọ tẹ́lẹ̀ rí fún iléeṣẹ́ tó ń rí ọ̀rọ̀ òkèrè Ethiopia, Nebiyu Tedla ni àwọn ń ṣe àmójútó ohun tó ń lọ ní Lebanon àti pé àwọn ń gbáradì láti kó àwọn èèyàn wọn kúrò.
Ọmọ orílẹ̀ èdè Ethiopia bíi 150,000 ló wà ní Lebanon, tí ọ̀pọ̀ wọn sì jẹ́ òṣìṣẹ́.
Ohun tó le ni pé òfin iṣẹ́ Lebanon kò fàyè gba òṣìṣẹ́ láti kúrò lábẹ́ ọ̀gá rẹ̀ láì gba àṣẹ lọ́wọ́ ọ̀gá bẹ́ẹ̀.
Fún Farai àti Sharon láti kúrò ní Lebanon rọrùn àmọ́ wọ́n fẹ́ dúrò láti parí ètò ẹ̀kọ́ wọn.
Àwọn méjéèjì ní àwọn pinnu lórí nǹkan tí àwọn bá fẹ́ ṣe lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀.












