Àwọn èèyàn n kú lọ́pọ́ ni Lebanon, bi Isreali ṣe n ju àdó olóró kiri

Oríṣun àwòrán, Reuters
Yatọ si Hasaan Nasrallah, olori ikọ Hezbollah ti Isreali pa, awọn eekan inu ẹgbẹ naa ti wọn tun ku iku ojiji lọjọ Ẹti to kọja, le ni ogun niye.
Awọn ọmọ ẹgbẹ Hamas fi idi iku wọnyi mulẹ lọjọ keji iṣẹlẹ naa.
Gẹgẹ bi ikọ iroyin Iran ṣe wi, wọn tun pa ọga ologun kan, Abbas Nilforoushan,sinu ikọlu naa.
Nigba to n sọrọ nipa ikọlu yii, Aarẹ ilẹ America, Joe Biden, ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii oṣuwọn idajọ.
Ṣugbọn olori agba ni Iran, sọ pe iku to pa Nasrallah ko ni i lọ bẹẹ lai jẹ pe awọn gbẹsan.
Ni gbogbo opin ọsẹ to kọja, ikọlu awọn Hezbollah ati Lebanon yii lo gba ori ayelujara kan, bẹẹ ni Israel kede pe awọn ti pa pupọ ninu awọn ọgagun alatako .
Ikọ Lebanon kede pe o le ni ọgọrun-un kan eeyan ti wọn pa lọjọ Aiku, o si ti le lẹgbẹrun kan eeyan to ti ku lapapọ bayii bi wọn ṣe sọ.

Oríṣun àwòrán, Goktay Koraltan/BBC
Ọmọdébìnrin yìí ń ṣeré nílée wọn ni tó fi lùgbàdì àdó olóró

Oríṣun àwòrán, Goktay Koraltan/BBC
Iku n polowo tan-an-tan-an kaakiri agbegbe ori oke Bekaa, ni Lebanon. Idi ni pe igbakigba ni iku le sọkalẹ le wọn lori lati oju ọrun pẹlu ado ooro
Ikọ ologun Isreali lo n ju ado oloro yipo ọjọ.
O kere tan, wọn n ju ọgbọn (30) laarin wakati kan lọjọ kan ṣoṣo.
Eeyan mẹrindinlaadọta (46) ni wọn ti kede iku wọn, bẹẹ ni onka naa si n pọ si i pẹlu.
Ọpọ lo wa nileewosan ti wọn n gba itọju lọwọ, lara wọn ni ọmọdebinrin kan, Noor Mossawi, ọmọ ọdun mẹfa to lugbadi ado oloro nibi to ti n ṣere nilee baba rẹ nibẹrẹ ọsẹ yii.
Ẹka itọju awọn ‘bi yoo ku tabi wọn yoo ye’, ni Noor wa nileewosan Rayak, nibi ti wọn ti we ori rẹ ni bandeeji, latari ado oloro to fọ ọ lori.
Ọjọ Aje to kọja ni Isreali fọ ọmọde naa lori pẹlu ado oloro.
‘Ẹ jọọ, ẹ ba mi ya aworan ọmọ mi, ọmọ ti ko mọ ohun to n jẹ nnkan ija, jẹẹjẹ rẹ lo n ṣere nigba ti ado oloro bẹrẹ si i dun.
‘’Ko sohun to kan wa pẹlu nnkan ija, Isreli kan fẹẹ maa daamu awọn eeyan ki wọn le maa sa kiri ni’’
Abdallah,Baba Noor lo sọrọ bẹẹ.
‘Ó lé ní irinwó èèyàn tó farapa, ọgọ́rùn-un ti kú nínú wọn’

Oríṣun àwòrán, Goktay Koraltan/BBC
Gẹgẹ bi Dokita Basil Abdallah, adari ileewosan kan lorilẹede naa ṣe sọ, o ni o irinwo eeyan ni wọn farapa ti wọn si gbe wa sileewosan lati ọjọ Aje to kọja, ọgọrun-un kan to ti ku ninu irinwo naa.
" O ba ni lọkan jẹ gan-an bi a ṣe n ri i ti wọn n ju bọmbu fu awọn ọmọde, awọn arugbo ati awọn obinrin.
‘’ Eeyan lawa naa, ẹjẹ wa lara wa, o si n dun wa ba a ṣe n ri awọn nnkan wọnyi.
‘’Awọn oṣiṣẹ wa paapaa ko ni idunnu mọ, pẹlu ibẹru ni wọn fi n ṣiṣẹ wọn’’
Ẹru to n ba Dokita Abdallah gẹgẹ bo ṣe sọ fun BBC, ni pe ki oogun ati awọn nnkan eelo ma lọ tan, nitori o ni ko jọ pe ogun yii yoo kasẹ nilẹ kia bo ṣe n lọ yii.
Lebanon ń la ìnira tó le jù kọjá báiìí nínú ìtàn ogun tó ti kojú wọn rí

Oríṣun àwòrán, Goktay Koraltan/BBC
Ilu kan to ti n koju ogun lati ọdun to ti pẹ ni Lebanon, kinni ọhun si ti su wọn, wọn lawọn ko fẹ gburoo ogun mọ.
Àpá ogun abẹle to ja wọn laaarin ọdun 1975 si 1990 ṣi n han lara wọn titi di asiko yii.
Bakan naa si ni ogun to waye laarin Hezbollah ati Israel ni 2006.
" Asiko yii lo buru ju ninu itan ilẹ wa. Inu mi bajẹ, b’awọn araalu si ṣe n ku lọpọ yanturu yii n ya mi lẹnu gan-an, afi bii pe ohun to n ṣẹlẹ yii ko tiẹ ja mọ nnkan kan.
"Israel fẹẹ maa pa wa lọ ni, k’Ọlọrun da aabo bo orilẹede yii.’’
Marwan Abboud, Gomina Beirut, lo sọ bẹẹ
Ile Lebanon ti wa lara awọn ibi ti wọn pe ni oju ogun bayii .
Ibeere ti ọpọ n beere ni pe njẹ Hezbollzah yoo da a pada fun Israel?
Ṣe awọn Iran, alatilẹyin wọn yoo da si i bii?
Ṣe Iraq, Syria ati Yemen yoo tun da si i ju bẹẹ lọ bi?
Ni bayii wọn ti kede ọjọ mẹta lati kẹdun awọn eeyan to ti ku, bẹrẹ lati ọjọ Aje lọ.
Ṣugbọn ko ti i si ẹni to mọ ibi ti rogbodiyan naa n lọ rara.














