Ṣé lóòtọ́ làwọn márùn ún kú lẹ̀yìn tí wọ́n jẹ ìpèsè ní ṣọ́ọ̀ṣì kan? Ohun tí ìwádìí wa fi múlẹ̀ nìyí

Àkọlé fídíò, Ṣé lóòtọ́ làwọn márùn ún kú lẹ̀yìn tí wọ́n jẹ ìpèsè ní ṣọ́ọ̀ṣì kan?
Ṣé lóòtọ́ làwọn márùn ún kú lẹ̀yìn tí wọ́n jẹ ìpèsè ní ṣọ́ọ̀ṣì kan? Ohun tí ìwádìí wa fi múlẹ̀ nìyí

Laipẹ yii ni iroyin kan gbode nipa awọn eeyan kan to di oloogbe lagbegbe Apata ni ilu Ibadan lẹyin ti wọn ni wọn jẹ ipese ninu ijọ alaṣọ funfun kan nibi.

Eyi lo sun BBC News Yoruba lati gba ile ijọsin naa lọ ati lati kan si awọn alaṣẹ eto ilera ni ipinlẹ Ọyọ lati fi idi ọr naa mulẹ.

‘Kii ṣe pe awọn eeyan jẹ ẹwa ninu ṣọọṣi wọn ku sibẹ’

Alagba Kilanko. Oluṣọ ijọ naa

Nigba ti A de ijọ CCC Apata Iye Provincial Headquarters ni agbegbe Apata, ẹni to jẹ oluṣọ ijọ naa, Alagba Akinwale Kilanko ṣalaye pe “lootọ ni wọn se ipese ẹwa ninu ijọ naa, eyi to tumọ si ase ifẹ ti gbogbo awọn ọmọ ijọ naa maa n jẹ papọ”.

Amọṣa o nikii ṣe ẹwa ti wọn jẹ lo fa wahala bikoṣe ajakalẹ aarun onigbmeji ti ijọba pẹlu gan ti fi idi rẹ mulẹ ṣaaju asiko yii.

Alagba Kilanko ni ọmọ oun obinrin gan ati ọmọ ti ọmọ rẹ yii bi pẹlu wa lara awọn to lugbadi aisan naa lẹyin ipese ọhun.

O ni ọjọ keji ni awọn bẹrẹ si ni gbọ iroyin loniranran nipa awọn ọmọ ijọ naa kan ti wọn n yagbẹ ti wọn tun n bi lẹyin ipese ọhun.o ni kete ti oun gbọ eyi ni oun ti paṣẹ pe ki wọn fi ọkọ ijọ ko wọn lọ si ile iwosan.

Ile igbọnsẹ ti ja pọ mọ kọnga ni ṣọọṣi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ - kọmiṣọna feto ilera ni ipinlẹ Ọyọ

Dokita Ajetunmọbi, kọmiṣọna feto ilera ni ipinlẹ Ọyọ.

Ninu ọrọ rẹ, kọmiṣọna fun eto ilera ni ipinlẹ Ọyọ, Dokita Oluwaṣẹrimi Ajetunmọbi ṣalaye pe ohun ti awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ilera ipinlẹ Ọyọ kẹẹfin nigba ti wọn lọ si agbegbe naa lati lọ fin ibẹ pẹlu awọn oogun apakokoro gbogbo to yẹ ni pe ‘o dabi ẹni pe ile igbọnsẹ ti wọn n lo ni ijọ naa ti ja lu’ ati wi pe pẹlu asiko ojo to wa nita, “o ti lọ dapọ pẹlu kọnga” ti wọn n lo ni ijọ naa.

Kọmiṣọna fun eto ilera naa tun tẹsiwaju pe ayẹwo ti wọn ṣe fun awọn eeyan naa lẹyin ti wọn ko wọn lọ si ile iwosan awọn aarun to ṣee tan kalẹ, fihan pe aisan onigbameji ni wọn ni.

Dokita Ajetunmọbi sọ pe nnkan bii aadọrin eeyan ni wọn ko wa fun itọju lati ile iwosan naa.

O ni gbogbo awọn eeyan agbegbe naa ti wọn ni arun yii ni wọn ti wa fun itọju ni ileewosan ijọba naa.

O ṣalaye siwaju sii pe nigba ti ijọba ipinlẹ Ọyọ gbọ iroyin ohun to ṣẹlẹ pẹlu bi awọn eeyan marun un kan ti ṣe gbẹmi mi lo jẹ ki wọn gbera lọ si ibẹ ti wọn si ko gbogbo awọn eeyan to ni afihan aisan naa wa si ile iwaosan ijọba to wa lagbegbe Olodo nibi ti wọn ti tọju gbogbo wọn ti awọn kan si ti gba ilera wọn.

Awa naa jẹ ninu ipese ọhun ko dẹ si nkan to ṣe wa, awọn ti wọn ko lọ si ileewosan aladani lo ku – Awọn ọmọ ijọ

Awọn ọmọ ijọ naa

Awọn ọmọ ijọ naa kan ṣalaye bi ọrọ ṣe jẹ. Wọn ni awọn pẹlu jẹ ninu ipese naa, awọn si rii pe ko si nnkankan to ṣe awọn.

Iyaafin Fatade Deborah to jẹ iya ijọ naa Ọgbẹni David Owoẹyẹ to jẹ ajihinrere ijọ naa ṣalaye pe ipese gangan kọ lo fa iku ati wahala awọn eeyan ti ọrọ kan nitori pe awọn pẹlu jẹ ninu ipese ọhun.

“Emi naa wa ninu awọn to jẹ ninu ipese yii ko dẹ si nnkankan to ṣe mi;” alagba Owoẹyẹ ṣalaye. Amọṣa o tẹsiwaju lati sọ pe, “Ohun ti emi ri ni pe kọlẹra wa nita, oun lo fa ohun to ṣẹlẹ.”

Iyaafin Fatade Adekọla ti oun pẹlu jẹ iya ijọ ij naa fi to wa leti pe awọn ti wọn ko lọ si ile iwaosan aladani lo ku ninu awọn eeyan naa.

Ninu ọrọ rẹ, o ni nigba ti wọn fi n wa owo kiri dipo ki wọn fi to awọn adari ijọ leti ni awọn eeyan naa fi jẹ Ọlọrun nipe nitori pe awọn ileewosan aladani kii gba lati ṣe iwosan laijẹ pe wọn ba ri owo.