Premier League: Liverpool fẹ́ gbafe yìí ṣá! Premier League yóò bẹ̀rẹ̀ padà lóṣù kẹfà

Oríṣun àwòrán, Twitter/Liverpool FC
Gbogbo eto ti to bayii lati bẹrẹ idije Premier League lọjọ kinni oṣu kẹfa ọdun yii lẹyin to ti wa nin idaduro nitori ajakalẹ aarun coronavirus.
Ohun ti awọn alaṣẹ idije naa n gbero ni lati gba gbogbo ifẹsẹwọnsẹ to ku tan laarin ọsẹ mẹfa ni kete ti idije naa ba ti bẹrẹ pada.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Inu ọpọlọ awọn ololufẹ idije Premier lo dun pe idije naa yoo pada laipẹ ọjọ.
- NFF fi #30,000 kún #10,000 owó ìrànwọ́ oṣooṣù fún ìyá Rashidi Yekini àti Samuel Okwaraji
- Olorì Aláàfin, Memunat Adeyemi, fohùn ránṣẹ́ sí ikú bàbá yèyé
- Coronavirus: Ǹjẹ́ àwọn dókítà tó ń tọ́jú eyín ń ṣisẹ́ lásìkò pàjáwìrì? Àti àwọn ìbéèrè míràn
- Àwọn nǹkan tí obìnrin lè ṣe pẹ̀lú olólùfẹ́ oníwà ipá lásìkò ìgbélé Coronavirus yìí
- Owó ìtanràn N40,000 ni mo san nítorí pé mí ò wọ ìbòmú- Vincent
- Ǹjẹ́ òògùn vitamin C lè pa coronavirus?
- Ǹjẹ́ ewé dongoyaro lè wo aàrùn coronavirus?
Ijọba ilẹ Gẹẹsi rọ awọn ẹgbẹ agbabọọlu ogun to wa ninu idije naa lati gba awọn ifẹsẹwọnsẹ to ku lawọn papa iṣere mii yatọ si ti wọn.
Ṣugbọn awọn ikọ agbabọọlu kọ jalẹ, wọn ni o wu awọn lati gba awọn ifẹsẹwọnsẹ to ku nile awọn.
Liverpool lo wa loke tente tabili EPL, nigba ti ifẹsẹwọnsẹ to ku si jẹ mọkanla.








