Brazil Yoruba: A n gbé àwọn ère Yorùbá káàkiri- Ọọni ti Ilé Ifẹ
Lẹyin ede Pọtugi, ede Yoruba ló kù ti wọn n sọ ju ni Brazil- Ooni Ifẹ
Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi to jẹ Ojaja 11 ti Ile Ifẹ nibi ojumọ ti n mọ wa saye ni iran Yoruba lo ni aṣa ati ede to dun.
O sọrọ yii nibi ayẹyẹ ayajọ ominira orilẹ-ede Brazil nilu Eko ni guusu Naijiria.
Nibi ayẹyẹ ominira Brazil yii ni Ile Ifẹ ti ṣafihan awọn ohun iṣembaye iran Yoruba fun ogo ilẹ̀ Yoruba.
Helge Bandeira to jẹ aṣoju orilẹ-ede Brazil ni Naijiria naa ṣalaye pataki iran Yoruba ni Brazil ati ifẹ fun aṣa ati ede Yoruba ti awọn ara Brazil ni pupọ.
Grassiano Oladipupo Martins to jẹ ọkan lara awọn ọmọ ọmọ Yoruba ti wọn bi si Brazil sọrọ lori ikonilẹru to sọ ọpọ ọmọ Yoruba di ero Brazil titi di oni.
Oba Ogunwusi mẹnuba igbesẹ ti ori ade fẹ gbe bayii nipa kiko awọn wura, idẹ, baba ati awọn ohun iṣẹmbaye iran Yoruba kaakiri awọn orilẹ-ede agbaye fun afihan aṣa ati awọn iṣe iran Yoruba.