Oniru: Oba Oniru wàjà ní Eko tẹbí, tará ń ṣe ìdárò Alayeluwa

Àkọlé fídíò, Oniru: Oba Oniru wàjà ní Eko tẹbí, tará ń ṣe ìdárò Alayeluwa

Bi eto isinku Kabiesi Oniru a ṣe lọ ni yii_-Arẹmọ Oniru.

Adeṣẹgun Oniru to jẹ arẹmọ Oba Oniru to waja ni ilẹ Iru ni ipinlẹ Eko ṣalaye bi eto isinku baba rẹ yoo ṣe ri fun BBC.

Adeṣẹgun ṣalaye pe, oku Oba nilẹ Yoruba yatọ si isinku ẹnikẹni yatọ si ori ade.

Awọn ẹlẹsin mẹtẹeta ni yoo jọ fọwọsopọ papọ ṣeto isinku Oba Oniru ni ọjọ ọtọọtọ ki wọn to wa ṣe aṣekagba lẹyin ogoji ọjọ pẹlu iranti baba baab Oba, iyẹ Oba Yesufu Oniru to waja ni 1984.

Arẹmọ naa ṣapejuwe baba rẹ pe ọrẹ bii baba ni Oba Oniru jẹ fun gbogbo awọn ọmọrẹ patapata.

Bakan naa ni BBC ba Musiu Obanikoro to jẹ Minista Abẹlẹ fun ọrọ ilẹ okeere tẹlẹ ni Naijiria sọrọ lori ipapoda Oba naa.

Obanikoro ni Oba to waja yii ko tọmọde tagba mọra ni.

O ni Kabiesi ni ifẹ pupọ fun idagbasoke ipinlẹ Eko ni eyi to hande ni bi agboole Oniru ṣe di nla bayii.

Ko si ẹni ti a ko ni ri lọjọ iku Erin ni ọrọ Oba to waja yii jẹ nipinlẹ Eko.

Muiz Banirẹ, Kọmiṣọna ri nipinlẹ Eko ṣapejuwe Oba to waja yii pe Kabiesi kii si nidii, ọtẹ, tabi ijẹkujẹ nibikibi.

O ni gbogbo ipinlẹ Eko ni yoo ṣafẹri Oba naa lẹyin to papoda yii.