Sport Betting: Idí rèé tí àwọn ọ̀dọ́ kan fi n ta tẹ́tẹ́...
Mo fi 2,000 ta... mo jẹ 7,500 -Collins.
Ibi gbogbo ni awọn eeyan ti n ta tẹtẹ ti ọpọ gba ni sogun dogoji.
Awọn ọdọ lasiko yii n ta tẹtẹ paapaa lori idije ere bọọlu alafẹsẹgba ati awọn idije ere idaraya miran kaakiri agbaye.
Nilẹ Adulawọ ikọ akọroyin oluwadii BBC Africa Eye ṣe iwadii tẹtẹ tita ni orilẹ-ede Uganda.
Ọrọ tẹtẹ tita ti fẹ di nkan miran nilẹ Adulawọ bayii nitori kaakiri ni awọn ṣọọbu tẹtẹ tita pẹlu ileeṣẹ loriṣiiriṣi to ti wa.
BBC Africa Eye, ọkan lara ẹka iwadiii ni BBC ṣe iwadii lori tẹtẹ tita ni Uganda paapaa ninu ere bọọlu alafẹsẹgba.
Ni eyi to fihan bi wọn ṣe n pin owo ti o fi ta tẹtẹ ati odiwọn iye ere rẹ.
Ifẹ ere bọọlu ati ọba lati ri owo gbọ bukata lo n jẹ ki ọdo miran ta tẹtẹ yii.
A ni lati daabo bo awọn ọdọ Naijiria ati ilẹ Adulawọ lapapọ lasiko yii kuro ninu tẹtẹ tita nitoripe ere rẹ ko pọ to ipalara inu rẹ.