Iléeṣẹ́ ààrẹ: Buhari kò bú ọdọ, àwọn ọ̀bàyéjẹ́ ń pa irọ́

Aarẹ̀ Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Iléeṣẹ́ ààrẹ ní ojúṣe ìjọba ni láti pèsè àyè tó tọ̀nà sílẹ̀ fún olúkúlùkù láti mú àlá rere wọn ṣẹ.

Lori ọrọ kan ti o n ja rayin-rayin ti wọn ni aarẹ Buhari sọ nilu London pe ọkundun ti ko fẹ iṣẹ ṣe lawọn ọdọ Naijiria.

Iroyin sọ pe ilu Lọndon ni Aarẹ Buhari ti sọ ọrọ naa lasiko to fi n ba igbimọ kan sọrọ nibi ipade awọn olori orilẹede to wa labẹ ajọ Commonwealth.

Ileese aarẹ orilẹede Naijiria ti sọ pe, ọrọ ko ri bẹẹ; atipe awọn ọbayejẹ ẹda kan lo fẹ ti ibi ohùn mu aarẹ.

Atẹjade kan ti olubadamọran fun aarẹ lori ọrọ iroyin, Fẹmi Adesina fi sita salaye rẹ pe, lootọ ni aarẹ sọrọ lori awọn ọdọ Naijiria, sugbọn ohun to sọ ni wi pe: "Awọn ọdọ pọ lorilẹede Naijiria, wọn si ko ida ọgọta ninu ọgọrun awọn eeyan orilẹede wa to to ọgọsan miliọnu eniyan.

aarẹ̀ Buhari ati ọbabinrin ilẹ Gẹẹsi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ààrẹ Buhari ní awọn eeyan Naijiria gbọdọ di opo iwa ootọ mu ki wọn si gbe igbe aye to duro daadaa

Atẹjade naa fikun wipe, ohun ti aarẹ so ni pe pupọ ninu awọn ọdọ wọnyii ti ọjọ ori wọn kere ju ọgbọn ọdun lọ ni wọn ko kawe, sugbọn ti wọn n pariwo epo rọbi wa lorilẹede Naijiria, nitorina ki wọn joye ajinasẹ, ki eto ileegbe, ilera ati ekọ ọfẹ o maa wọle tọ wọn wa bẹẹ"

Atẹjade naa ni ko si bi aarẹ Buhari yoo na ika kòtọ si àwọn ọdọ orilẹede Naijiria nitoripe baba awọn ewe ati ọdọ orilẹede Naijiria ni.

Ileesẹ aarẹ ni, ibi gbogbo lati n kadiyẹ alẹ, ko si ibi ti awọn ọlẹ afàjò ko si, ṣugbọn ojuṣe ijọba lẹka gbogbo ni lati pese aye to tọna silẹ fun olukuluku lati mu ala rere wọn ṣẹ.

Iru awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: