Ọdún Gbàgede Oro, àkọ́kọ́ irú rẹ̀ rèé, èyí tó ṣàfihàn àṣà Yorùbá, tí Aláàfin Oyo sì súre fún wọn
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
Ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan ti wọn jẹ ọmọ bibi ilu Oro nipinlẹ Kwara ati awọn alejo lo ya wọ ilu naa.
Ọdun Gbagede Oro ti ọdun yii si ni wọn peju lati se,
Se ni ilu Oro n sọkutu wọwọ lasiko ọdun naa nibi ti awọn eeyan ti se afihan asa isẹdalẹ Yoruba ati tilu naa.
Igba akọkọ si ree tawọn eeyan ilu naa yoo peju se ajọyọ papọ eyi ti wọn pe ni Gbagede Ọba.

Bakan naa, Oloro tilu Oro, Ọba Joel Oyatoye ati Olori rẹ safihan asọ ibilẹ wa ninu asọ oke kan naa ti wọn wọ.
Lara awọn alejo pataki to ba wọn peju sibi ọdun Gbagede Oro naa ni Alaafin tilu Oyo, Ọba Abimbola Akeem Owoade.
Se ni ilu n dun lakọ lakọ, tawọn eeyan si n fo fẹrẹ fun ayọ lasiko ajọdun naa.
BBC Yoruba ba wọn peju sibi ọdun Gbagede Ọba nilu Oro, ohun ti a mu bọ ree ninu fidio yii.
















