"Àwá òṣèré tó lé ní 100 la polongo ìbò fún Tinubu fún oṣù méjì àmọ́ kò fún wa ní nkànkan, mo kábàmọ́ọ̀ pé mo polongo ìbò fún"

Oríṣun àwòrán, Ayeni Abayomi/Facebook
Agbaọje oṣere ori itage Yoruba, Ganiu Nafiu, ti ọpọ mọ si Alapini ti sọ pe oun kabamọ pe oun polongo ibo fun Aarẹ Bola Tinubu lọdun 2023.
Alapini sọrọ yii ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe lori tẹlifisan African A-List TV nibi to ti sọ nipa bo ti bẹrẹ iṣẹ ere ori itage ati awọn ipenija ilera to ti koju.
Ọgbẹni Nafiu sọ pe nnkan to buru jai ni bi Tinubu ati ọmọkunrin rẹ, Seyi Tinubu, ko ṣe ranti awọn oṣere to le ni ọgọrun mọ lati ṣe nnkan fun wọn tori atilẹyin ti wọn se fun.
Gbajugbaja oṣere naa sọ pe awọn ri Tinubu gẹgẹ bi ẹni ti yoo ṣe daadaa fun araalu, lo jẹ kawọn ṣe ipolongo fun un tori o ti maa n ṣe daadaa sawọn elere ori itage tẹlẹ.
Amọ, o ni o ṣeni laanu wi pe ireti tawọn ni ninu Tinubu ti di ijakulẹ bayii.
Alapini sọ pe oun atawọn akẹgbẹ oun tawọn le lọgọrun fi oṣu meji polongo ibo fun Tinubu ni ireti wi pe yoo ranti awọn to ba wọle ibo naa tan.
Gbajugbaja oṣere naa sọ pe iyalẹnu lo jẹ foun pe Tinubu ati ọmọkunrin rẹ Seyi ko tii ṣe nkankan fawọn, lati mọ riri ohun tawọn ṣe fun aarẹ lasiko ipolongo ibo lọdun 2023.
''Ṣe Seyi maa sọ pe oun ko ri awọn agba oṣere to jade lati ṣe ipolongo ibo fun baba rẹ ni?
Ni ṣe ni gbogbo wa n rin kaakiri laarin ọja lai ṣe were lati polongo ibo fun Tinubu ati agba ati ọmọkekere ninu wa.
Koda, a tun lọ ṣe ipolongo ibo lawọn ibikan tawọn mii ko le wọ, ṣugbọn wọn o fun wa ni nnkankan,'' Alapini lo sọ bẹẹ.
Epe rabandẹ lawọn eeyan n ṣẹ le wa lori lasiko ti a n ṣe ipolongo ibo fun Tinubu - Alapini
Alapini tẹsiwaje pe ''Epe rabandẹ lawọn eeyan n ṣẹ le wa lori lasiko ti a n ṣe ipolongo ibo naa papaa julọ lori ayelujara.
Epe ti wọn ṣẹ fun ọrẹ mi Olaiya Igwe to bọ ara rẹ si ihoho leti okun lati polongo ibo fun Tinubu tiẹ pọju.
Olaiya ko tii bọ lọwọ gbigba epe titi di oni, wọn si tun n fi epe ranṣẹ si i,'' Alapini ṣalaye.
Alapini tun sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo naa pe ko sẹni to fun Olaiya ni ọkọ , gẹgẹ bii awọn eeyan kan ṣe n sọ lori itakun ayelujara.
Nigba ti wọn beere lọwọ agbaọjẹ oṣere naa bo ya yoo tun ṣe ipolongo ibo fun Tinubu fun saa keji ṣaaju ibo aarẹ ọdun 2027, Alapini ni oun ko tii ronu nipa rẹ.
Agbaọjẹ oṣere naa tun bẹnu ẹtẹ lu awọn eto ti Seyi Tinubu n ṣe lapa ariwa Naijiria lati ṣe iranwọ fawọn ti ko rọwọ họri lawujọ.
O ni ko dara bi Seyi ti pa awujọ Yoruba ti pẹlu eto ti o n ṣe yii.
''Seyi Tinubu wa n kaakiri apa ariwa, o n san owo itọju awọn alaisan nile iwosan.
Ile iwosan meloo nilẹ Yoruba ni Seyi ti ṣabẹwo si lati sanwo itọju awọn alaisan?'' Alapini lo beere bẹẹ.















