Tinubu, Atiku sọ̀rọ̀ sókè lórí ìkọlu Benue bí àjọ NEMA ṣe ní ẹ̀mí èèyàn tó lé ní 100 ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ

Oríṣun àwòrán, @Asarailu_
Aarẹ Bola Tinubu ti ba awọn eeyan ipinlẹ Benue kẹdun lẹyin ikọlu awọn afurasi darandaran to mu ẹmi eeyan to le lọgọrun lọ ni abule Yelewata, to wa ni ijọba ibilẹ Guma.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Bayo Onanuga fi lede, Tinubu ke si awọn adari ileeṣẹ ọmọ ogun lati wa ojutu si iṣẹkupani to n waye lemọlemọ ni Benue.
Onanuga sọ pe lẹyin aṣẹ Tinubu, awọn ọga agba nileeṣe ologun Naijiria ti tẹkọ leti lọ si ipinlẹ ọhun.
Tinubu kilọ fun awọn adari oṣelu ati ori ade lagbegbe naa ki wọn ṣọra fun irufẹ ọrọ ti yoo maa ti ẹnu wọn jade, eyii to le tunbọ fẹ ọrọ naa loju si.
O ni "Iroyin ikọlu tuntun to tun waye ni Benue ba mi ninu jẹ pupọ, a ko gbọdọ faye gba irufẹ iṣẹlẹ bayii lati tẹsiwaju lati maa tẹsiwaju. O ti to gẹ.
"Mo ti ke si awọn adari ologun lati fi ṣikun ofin mu awọn to wa nidi ikọlu yii ati gbogbo igun to lọwọ ninu rẹ ki wọn si jẹjọ.
"Asiko ti to fun gomina Alia lati ṣe bii adari rere lati pe gbogbo awọn ti ọrọ kan lati jiroro lori bi wọn ṣe le pari aawọ to n waye nibẹ ki alafia le jọba ni Benue."
Ẹwẹ, ileeṣẹ Aarẹ ti juwe ikọlu ọhun gẹgẹ bii ẹsan ikọlu to waye tẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, @nemanigeria
Eeyan to le ni ọgọrun un ni wọn pa ni Benue – NEMA
Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni Naijiria, NEMA, ti fidi rẹ mulẹ pe o le ni ọgọrun eeyan ti awọn agbebọn ṣekupa ni Benue.
NEMA lo fidi ọrọ naa mulẹ ninu atẹjade kan to fi lede loju opo X rẹ bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan to lọ sibẹ bii ajafẹtọọmọniyan, Very Dark Man ni awọn to ku le ni igba.
Ninu ọrọ NEMA, o ni "A ko tii le sọ ni pato iye eeyan to ba iṣẹlẹ naa lọ latari eto abo to mẹhẹ lagbegbe naa ati bo ṣe ṣoro lati de ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.
"Amọ awọn iwadii ti a ti kọkọ ṣe fi han pe awọn to ku le ni ọgọrun un, ṣugbọn a maa mọ si bi a ṣe n tẹsiwaju ninu idoola ti a n ṣe lọwọ.
"Ọpọ eeyan lo farapa, a gbe awọn mẹrindinlaadọta lọ ile iwosan amọ o ṣeni laanu pe ogun eeyan ninu wọn lo pada ku.
"O le ni ẹgbẹrun mẹta eeyan – ti ọmọde atawọn obinrin wa ninu wọn - to ti padanu ile wọn, gbogbo wọn lo nilu ounjẹ, oogun, aṣọ atawọn nnkan mii bayii.
Ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Benue gbọdọ bẹrẹ iwadii ni kankan – Atiku Abubakar
Igbakeji Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Atiku Abubakar ti ke si ijọba apapọ lati gbe iwadii dide lori iṣẹlẹ naa, ko si ri daju pe iru rẹ ko ṣẹlẹ mọ.
Atiku sọ pe ikọlu naa ba oun ninu jẹ, kii si ṣe ikọlu abule kan ṣa amọ o jẹ eyii ti ijọba apapọ gbọdọ fi ọwọ pataki mu.
O fi kun pe ijọba gbọdọ ṣewadii gbogbo awọn to lọwọ ninu rẹ ki wọn si fi imu wọn danrin.
Igbakeji Aarẹ tẹlẹ ọhun fi kun pe ijọba apapọ gbọdọ pese aabo to peye fun awọn eeyan ipinlẹ Benue ki irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ ma ba waye mọ.
Ẹwẹ, ajọ Amnesty International ti bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa.
Ajọ ọhun tun ke si ijọba Naijiria lati sa ipa rẹ lati ri daju pe irufẹ iṣẹlẹ naa ko waye mọ.
Ohun tá a mọ̀ nípa ìkọlù àwọn agbébọn tó ṣekúpa ọ̀pọ̀ èèyàn ní Benue

Oríṣun àwòrán, Attah Edeh
Ikọlu awọn agbebọn tuntun ti gba ẹmi ọpọ eeyan ni abule kan nipinlẹ Benue ni apa ariwa orilẹede Naijiria.
Iṣẹlẹ yii lo waye ni Yalawata, ilu kan to wa ni ẹnu ibode ipinlẹ Nasarawa ati Benue, ti awọn alaṣẹ si ti fi di iṣẹlẹ naa mulẹ.
Gomina ipinlẹ Benue Hyacinth Alia ti bu ẹnu atẹlu iṣẹlẹ naa to gba ẹmi lẹnu ọpọ eeyan ti mọ ohunkohun ni Yelewata, o ni "ko si ẹnikẹni to ni ẹtọ lati gba ẹmi lẹnu ẹlomiiran."
Awọn alaṣẹ ni o le ni eeyan marundinlaadọta to padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ to waye ni aṣalẹ mọju.
Oṣojumikoro ni awọn darandaran to gbe ibọn dani lo kọlu agbegbe naa, ti wọn si tun koju ọlọpaa.
Ọpọ ile ni wọn dana sun niluu Yelewata.
Ni ọjọ Aiku, awọn ọdọ agbegbe naa tu sita lati ṣe ifẹhonuhan tako iṣekupani to waye.
Awọn olufẹhonuhan ni korajọ ni agbegbe Wurukum niluu Makurdi to jẹ olu ilu ipinlẹ naa.
''Pẹlu igbagbọ alaafia ati isọkan, a n kesi awọn olori ẹṣin ati awọn oloṣelu kaakiri ipinlẹ lati ke si awọn ọdọ to n korawọnjọ ni ọna ti ko bao fin mu ." Gomina Alia sọ.
Ni ọjọ meji sẹyin, eeyan to le ni mẹdọgbọn lo padanu ẹmi wọn niluu Makurdi yii.
Bakan naa ni ọsẹ meji sẹyin, eeyan mẹdọgbọn mii padanu ẹmi wọn.
Gomina Alia rawọ ẹbẹ si awọn araalu lati lo ọna ti ijọba ti pese lati kesi wọn ti wọn ba kẹfin iwa ọdaran.
"Ipinlẹ Benue yoo ri pe idajọ ododo, alaafia ati aabo fun awọn araalu". Gomina sọ.
Igbakeji Gomina ipinlẹ, Sam Ode ṣabẹwo si agbegeb ti iṣẹlẹ naa ti waye ni owurọ ọjọ Aiku, to si ni Gomina n ṣiṣẹ takuntakun lati gba alaafia laye.
Gomina Alia ti fi da awọn araalu loju pe awọn ti ṣe afikun eto aabo nipinlẹ naa lati doola ẹmi ati dukia awọn eeyan.
"Ọpọ awọn agbofinro ti wa nipinlẹ Benue bayii lati ọdọ ijọba apapọ".
Aworan lati ibi ikọlu naa

Oríṣun àwòrán, Others

Oríṣun àwòrán, Others












