Ọkọ̀ òfúrufú ẹlikọ́pítà já lulẹ̀ ní India, èèyàn méje kú

Oríṣun àwòrán, @Hinduism_sci
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
Eeyan meje lo ti jade laye lẹyin ti ọkọ ofurufu ẹlikọpita kan ja lulẹ lagbegbe Uttarakhand, lorilẹ India India.
Awọn alaṣẹ orilẹede naa lo fi iroyin ọhun lede.
Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle jabọ pe ilu Dehradun ni ẹlikọpita naa ti n lọ si agbegbe Himalayan, nibi ti ọpọ ori oke wa ti awọn olujọsin ti maa n pade.
A gbọ pe ni kete lẹyin iṣẹlẹ naa ni awọn adoola ẹmi korajọ sibẹ lati gba awọn ti ọrọ naa kan la.
Lara awọn to ku ni awakọ ofufuru naa ati ọmọ ọdun mẹsan an kan.
Ileeṣẹ to n ri si ọrọ ọkọ ofurufu nilẹ naa ti sọ pe ajọ Aircraft Accident Investigation Bureau (AAIB) to n ṣe iwadii ijamba oju ofurufu ni yoo ṣewadii ohun to ṣokunfa ijamba ọhun.
Iroyin yajoyajo ni iroyin yii, a o maa ṣe afikun rẹ laipẹ.











