Ariwo ta bí iléeṣẹ́ ọ̀gbìn ṣe ní káwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ààwẹ̀ àti àdúrà kí oúnjẹ le pọ̀ ní Nàíjíríà

Ariwo nla ti sọ ni orilẹede Naijiria, bi ileesẹ eto ọgbin se kede pe ki awọn osisẹ rẹ gunle eto adura gbigba kikankikan, ki orilẹede yii lee ni ounjẹ lọpọ yanturu.
Iwe kan ti olori fun ẹka alarina fun ileesẹ eto ọgbin nilẹ Naijiria fisita, lo n rọ awọn osisẹ nileesẹ naa lati peju sibi adura kan, ki wọn si tun gba aawẹ ni ọjọ Aje mẹta.
Atẹjade naa ni wọn kọ ni ọjọru, ọjọ Kọkanla osu kẹfa ọdun 2025 si gbogbo osisẹ ni ẹka eto ọgbin, to fi mọ awọn oludari, igbakeji oludari, oluranlọwọ fawọn igbakeji oludari atawọn ipẹẹrẹ osisẹ nileesẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Adedayo Modupe
"Ọjọ Aje mẹta to tẹle ara wọn, eyiun ọjọ Kẹrindinlogun, ikẹtalelogun ati Ọgbọnjọ osu Kẹfa ni eto aawẹ ati adura naa yoo maa waye"
Atẹjade ọhun, ti Oludari fun ẹka alarina, Arabinrin Adedayo Modupe O fọwọsi lo salaye pe ki awọn osisẹ gbogbo nileesẹ eto ọgbin peju si olu ileesẹ eto ọgbin nilu Abuja feto adura gbigba ati aawẹ.
Igbesẹ naa si lo ti n fa awuyewuye laarin awọn ọmọ Naijiria nipa pipe akiyesi ijọba si ojuse pataki to ni lati mu ki owo ounjẹ to wọn gogo wa silẹ pada.
Ọjọ Aje mẹta to tẹle ara wọn eyiun ọjọ Kẹrindinlogun, ikẹtalelogun ati Ọgbọnjọ osu Kẹfa ni atẹjade naa sọ pe eto aawẹ ati adura naa yoo maa waye.
Atẹjade lati ileesẹ eto ọgbin naa ti wa mu ki awọn araalu maa fi oju tẹmbẹlu aayan ijọba lẹka eto ọgbin.
Wọn ni kii se igbesẹ to dangajia ni fun ẹka isejọba kan lati maa pe fun adura ati aawẹ gbigba lati kọju oro si ọwọngogo ounjẹ, bikose lati mu ki alaafia ba agọ ara awọn osisẹ naa.
Ileesẹ eto ọgbin pa ohun da lori ikede aawẹ ati adura to se, o gbẹsẹ le eto naa
Wayi o, Ileesẹ eto ọgbin nilẹ wa ti pa ohun da lori ikede aawẹ ati adura to se, to si ti gbẹsẹ le eto naa.
Atẹjade miran to tẹlẹ ti isaaju yii, eyi ti Oludari fun ẹka alarina ileesẹ naa tun fisita lo n kede pe wọn ti so eto adura ati aawẹ gbigba naa rọ di ọjọ miran.
Amọ ko salaye idi ti wọn fi sun igbesẹ naa siwaju.















