Mo ní kí ọkọ mi fẹ ìyàwó kejì, ṣùgbọ́n ó kọ̀ - Ìyàwó pásítọ̀ tó yàgàn fún ọdún 24 kó tó bí ìbejì

Oríṣun àwòrán, Punch
Obinrin kan to tun jẹ alufaa ninu ijọ MFM ti ṣalaye bo ṣe ya agan fun odidi ọdun mẹrinlelogun amọ ti ko sọ ireti nu pe oun ṣi maa di ọlọmọ laye.
Alufaa Funmilola Abraham, ṣalaye pe ọdun 2001 ni oun ṣe igbeyawo lẹni ọdun mẹtalelọgbọn ki oun to di ọlọmọ lẹni ọdun mẹtadinlọgọta.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, oniruru iṣoro ati ipenija loun ati ọkọ oun dojukọ ninu irinajo igbeyawo wọn amọ o fi ireti rẹ sinu Ọlọrun MFM pe oun naa yoo di ọlọmọ laye.
Oniruru ile iwosan ni a lọ amọ ko si ọna abayọ

Oríṣun àwòrán, Funmilola Abraham
Ninu ifọrọwerrọ pẹlu ileeṣe iroyin Punch, Funmilola Abraham sọ pe oun ṣiṣẹ abẹ oyun iju lọdun 2002 ti awọn dokita si sọ pe ko si ewu mọ lẹyin iṣẹ abẹ ọhun.
O ni "Ọkọ mi lọ ṣe ayẹwo ara rẹ wọn ni ko sewu, lati igba naa ni a ti ko si, ti a si n lọ lati ile iwosan kan si omiran fun ọna abayọ.
"Mo ti ṣe nnkan ti wọn n pe 'flushing' bii igba mẹwaa, sibẹ pabo lo ja si.
"Nigba ti yoo di ọdun 2019 ni mo lọ ṣe IVF, lagbara Ọlọrun, o ṣiṣẹ, mo si loyun ibẹta."
Obinrin naa ṣalaye pe lẹyin oṣu marun ni awọn oniṣegun sọ pe awọn ibẹta naa ko mi daa, wọn ni ọkan wọn ko ṣisẹ daadaa.
"Lẹyin naa ni wọn ṣe D&C fun mi ti mo si padanu awọn ọmọ mẹtẹta ọhun."
Mo sọ ireti nu ninu awọn dokita, mo si fi ireti mi sinu Ọlọrun nikan ṣoṣo
Alufaa Funmilola Abraham sọ siwaju si pe lẹyin ijakulẹ naa loun fi ireti oun sinu Ọlọrun ni kan ṣoṣo.
O ni "Lẹyin naa mo ṣe IVF mii amọ ko yọri si rere.
"Lẹyin naa ni mo boju wo oke ti mo si sọ pe 'Oluwa, mo ti ṣe iwọn ti mo le ṣe gẹgẹ bii eniyan. '
"Lẹyin naa ni m o fi ireti mi sinu Ọlọrun ti mo si gbajumọ iṣẹ iranṣẹ... mo tẹsiwaju lati maa ṣe ohun ti Oluwa pe mi si.
Mo ni ki ọkọ lọ fun obinrin mii loyun amọ o kọ jalẹ

Oríṣun àwòrán, Funmilola Abraham
Alufaa obinrin naa ni oun gba ọkọ lamọran lati lọ fẹ ẹlomiran labule ṣugbọn ṣugbọn ko gba gẹgẹ bii ọmọ Ọlọrun tootọ.
O ni "Mo dupẹ fun ọkọ mi; Kristẹni to ti di atunbi ni.
"Lakoko kan, mo sọ fun pe lọ si abule ki o lọ fẹ iyawo mii gẹgẹ bii Sarah ṣe ṣe ṣugbọn o ni 'Ki lo n ṣe lẹnu yii? Ṣe mi o ri eeyan labule tẹlẹ ki n to fẹ ẹ ni? Mi o lọ sibi kankan."
Ẹwẹ, bo tilẹ jẹ obrinin naa ko tii bimọ, ọpọ igba lawọn eeyan maa n lọ gbadura ọmọ bibi lọdọ rẹ ti yoo si gbadura fun wọn, ti awọn eeyan naa yoo si pada wa gbegba ọpẹ.
Lẹyin-o-rẹyin, Funmilola Abraham bi ibeji lantilanti lọjọ kejila, oṣu Kẹta, ọdun 2025 yii.
Ninu orọ iyanju rẹ si awọn to n wo oju Oluwa fun ọmọ, o ni ki wọn tete gbe igbesẹ ti wọn ba fẹ ṣe IVF.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, irufẹ obinrin bẹẹ gbọdọ ṣe IVF ọhun lasiko ti wọn ba wa lẹni ọdun mẹtadinlogji si ogoji ọdun.














