Wo bí fóònù ṣe ń ṣokùnfà ikú àwọn obìnrin tó wà nílé ọkọ ní Niger

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni orilẹede Niger, Ajọ ẹsin Islam to ga julọ lorilẹede naa ti di ẹbi iku ọwọọwọ laarin igbeyawo lorilẹede naa ru ohun mẹta: igbeyawo olorogun, ẹrọ ibanisọrọ alagbeka ati ọti mimu.
Ajọ naa ti wọn gba kalẹ fun yiyanju aawọ laarin lọkọlaya ṣalaye pe, laarin ọdun 2024 nikan, ẹgbẹrun kan le irinwo ati mẹtalelọgbọn (1433) igbeyawo ni wọn tuka ni olu ilu orilẹede naa nikan ti wọn si tun ẹgbẹrun meji ati ẹẹgbẹta o le marundinlaadọrin (2565) miran to.
Ki ni ipa ti ẹrọ ibanisọrọ alagbeka ko?
Arakunrin kan lorilẹede Niger naa, ti orukọ rẹ n jẹ, Isa Karimu sọ pe o yẹ ki awọn olori ẹsin lorilẹede naa tubọ maa sa ipa lati waasu fun awujọ pe iṣẹ ẹsin ni igbeyawo jẹ ki wọn si mọ irufẹ akoba ti ẹrọ ibanisọrọ n ko ninu rẹ.
"Bi mo ba ti n wọle ni mo maa n pa ẹrọ ibanisọrọ mi, o si tun di igba t imo ba n jade ki n to tun tan an. Nitori ni kete ti foonu ba dun ọkan ẹni to ni foonu yoo lọ si ara rẹ, bẹẹni bi ọkunrin ba gbọ ti foonu iyawo rẹ dun ọkan rẹ pẹlu yoo lọ sibẹ.
"Awọn Imaamu gbọdọ maa ṣe iwaasu ni mọṣalaṣi lọjọ Ẹti lati pe akiyesi ọkunrin ati obinrin si ọrọ ajọṣepọ lọkọlaya."
'Igbeyawo kan wa to tuka lọjọ ti wọn ti wọn so lọkọlaya pọ'
Nana Hadiza to jẹ ajafẹtọ ni Yamai ṣalaye pe, "Igbeyawo kan wa to jẹ pe iyawo ko sun ile ọkọ rẹ lalẹ ọjọ igbeyawo wọn. Ọkọ gbe iyawo rẹ si inu ọkọ lalẹ ọjọ naa o si wa a lọ si ile awọ obi rẹ."
Nana Hadiza di ẹbi ọrọ ru igun gbogbo ti ọrọ kan bi o tilẹ jẹ wi pe ko fi bẹẹ si itaniji pupọ bẹẹ lori ẹtọ awọn obinrin, eyi to ni oun pẹlu n pa kun ipenija naa.
"Ko si iyi fun awọn obinrin, ko si ẹtọ fun awọn obinrin, koda awọn obinrin funrawọn ko mọ ẹtọ wọn ninu igbeyawo. Bakan naa ni ko mọ ẹtọ ti Eledumare fi fun oun ati ọkọ rẹ ninu igbeyawo wọn.
"Nitorinaa waa rii pe awọn igbeyawo naa yoo waye, ṣugbọn kii ja si bi erongba wọn lori rẹ ṣe fẹ."
Ipa ti aigbepọ lọkọlaya pẹlu n ko
Lorilẹede Niger, awọn obinrin kan ti ọkọ wọn n gbe nilẹ okeere labẹ eto pe wọn n wa ko ledaa lọ soke okun tabi japa pẹlu n ba ipenija nla pade nitori aopada wa sile ọkọ wọn lasiko. Eleyi si maa n ja si iku wọn lọpọ igba.
Pupọ awọn obinrin to ba BBC sọrọ sọ pe ọpọlọpọ ọdun ni ọkọ awọn ti lo nilẹ okeere ṣugbọn ti ko pada wa sile.
Eyi ti mu ki ọpọlọpọ igbeyawo tuka.Hajiya Aisha, ti a ko da orukọ rẹ gangan wa lara awọn obinrin to ba BBC sọrọ; o ni ọkọ oun lọ si orilẹede Amẹrika lọdun marundinlogun sẹyin, ko sit ii dari wale.
Gẹgẹbi o ṣe sọ, "Gbigbe nibi ti su mi, ṣugbọn awọn obi mi ko fẹ ki n ja iwe ikọsilẹ fun un".
Awọn obinrin naa sọ pe lootọ awọn ọkọ wọn n fi owo ranṣẹ, sibẹ ko tẹ awọn lọrun bii ko jẹ wi pe ọkọ awọn lo dari wa sile.















