Njẹ́ o ti gbọ́ nípa Labubu, ìlúmọ̀ọ́ká bèbí tí wọ́n n tà ní $150,000?

Aworan bebi Labubu

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Bebi kan ti orukọ rẹ n jẹ Labubu to dabi eeyan ni wọn ti ta ni $150,000 lọsẹ yii ni China.

Bebi ọhun to ga to iwọn ẹsẹ bata mẹrin ni wọn ta nibi eto kata-kara Yongle Int'l to waye niluu Beijing.

Ẹni to ṣagbatẹru kata-kara ọja naa ti sọ pe bebi yii ni nnkan iṣere ọmọde to wọn julọ lagbaaye bayii.

Oniṣẹ ọna, ọmọ ilu Hong Kong kan, Kasing Lung, lo ṣe bebi Labubu ni bii ọdun meloo kan sẹyìn.

Bebi naa si ti di nnkan ti ọpọ eeyan n sọ nipa rẹ lẹyin t'awọn gbajumọ láwùjọ buwọ lu u.

Ile itaja Pop Mart ni China maa n ta bebi Labubu ni aadọta owo yuan.

Koda, bebi Labubu ni wọn fori eto kata-kara to waye lọsẹ yii sọ.

Ọja bii mejidinlaadọta ni wọn patẹ lati ta a pẹlu onibaara igba ti wọn fẹ ra oniruuru nnkan.

Ko din ni miliọnu mẹta ati ọọdunrun un owo yuan ti awọn ontaja ri nibi kata kara naa.

Ọpọ eeyan lo ti bẹrẹ si ni maa sọ nipa bebi Labubu kaakiri agbaye lẹyin ti obinrin kan to n jẹ Lisa fi aworan rẹ sori ayelujara.

Darapọ mọ Whatsapp Channel BBC Yoruba fun ajaabalẹ iroyin

Skip Tẹ oju opo yii lati darapọ mọ wa ni Whatsapp Channel and continue readingTẹ oju opo yii lati darapọ mọ wa ni Whatsapp Channel

End of Tẹ oju opo yii lati darapọ mọ wa ni Whatsapp Channel

Rihanna, David Beckham, ati awọn gbajumọ to sọ Labubu di gbajumọ

Awọn eeyan tun ti bẹrẹ si ni mọ nipa bebi naa lori TikTok lẹyìn ti gbajugbaja akọrin n ni, Rihanna ati ilumọọka Lipa Dua wọ ọ sara.

Balogun ẹgbẹ agbabọọlu England tẹlẹ, David Beckham naa fi fọto bebi Labubu soju opo Instagram rẹ.

Ṣaaju ninu ọdun yìí ni ile itaja Pop Mart China ti kọkọ ko bebi Labubu kuro lorileede UK lẹyìn ti iroyin kan sọ pe awọn onibaara n ja si i.

Apati ni wọn fi maa n saba fi ta bebi Labubu ni China.

Bi bebi Labubu ṣe di ilumọọka ti jẹ ki ọpọ eeyan gbọ nípa ile itaja Pop Mart.

Owo ti ko din ni mílíọ̀nù mẹtala yuan ni ere ti ile itaja naa kede lọdun 2024, eyi to ju ilọpo meji ohun tí wọn ri lọ lọdun 2023.

Koda, orilẹede marun un ni wọn ti da ile itaja Pop Mart silẹ lọdun to kọja eyi ti Spain ati Italy wa lara wọn.